Ìjọba àpapọ̀ kọminú lórí bí àwọn ọmọ Naijiria ṣe ń lọ jagun nílẹ̀ òkèrè láì mọ̀

Ogun Ukraine ati Russia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba Naijiria ti kọminu lori bi awon ọmọ orilẹede rẹ ṣe n darapọ mọ awọn ọmọ ogun ilẹ okere lati kopa ninu ogun ti wọn n ja lọwọ.

Ninu atẹjade kan lọjọ Aiku, agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ilẹ okere, Kimiebi Imomotimi Ebienfa, sọ pe awọn ilẹ okere kan n tan ọmọ Naijiria ẹ lati mu ki wọn lọ jagun nilẹ okeere laimọ.

Awọn alaṣẹ ni wọn n tan awọn ọmọ Naijiria kan jẹ pẹlu iṣẹ ati eto ẹkọ ọfẹ nilẹ okere ki wọn le lọ fi wọn jagun.

Lọsẹ to kọja ni ijọba ilẹ Ukraine sọ pe awọn ri oku ọmọ Naijiria meji lagbegbe Luhansk.

Wọn ni ṣaaju iku wọn lawọn oloogbe naa ti kọkọ tọwọ bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ ọmọ ogun Russia lọdun 2025, ti Russia si ran wọn lọ soju ogun lai ni imọ kankan nipa ogun jija.

Gẹgẹ bii ohun ti Ukraine sọ, inu oṣu Kọkanla ọdun to kọja ni wọn ṣekupa awọn ọmọ Naijiria naa lasiko ti wọn n kọju ija si Ukraine labẹ akoso Russia.

Ijọba Naijiria ninu ọrọ rẹ ni eto ẹkọ, iṣẹ olowo gọbọi ati ileri lati sọ wọn di ọmọ oniluu ni wọn fi n tan awọn ọmọ Naijiria kan lati lọ jagun nilẹ okere.

Atẹjade ijọba Naijiria

Oríṣun àwòrán, @NigeriaMFA

Nigba mi ẹwẹ, wọn ni wọn maa n fi agidi mu awọn ọmọ Naijiria lati tọwọ bọwe ti wọn kọ ni ede ti wọn ko le ka, wọn yoo si tun gbẹsẹle iwe irinna wọn ti wọn ba ti de ilẹ okere ọhun tan.

Ọgbẹni Ebienfa kilọ fun awọn ọmọ Naijiria ki wọn ṣọra fun gbigba irufẹ iṣẹ bẹẹ nitori yoo fi aye wọn sinu ewu, bẹẹ ni o tun le lodi si ofin agbaye to rọ mọ ṣiṣe iṣẹ ajagunta.

Ijọba ni oun n ṣiṣẹ pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ lati ṣewadii iṣẹlẹ naa ati pe oun ti bẹrẹ eto itanji fun awọn araalu.

Iwadii lati Ukraine fi han pe o le ni ẹgbẹrun kan ati irinwo ọmọ ilẹ Afrika ti wọn ti fi ẹtan gbe lọ lati maa jagun fun Russia.

Wayi o, awọn kan naa tun ti bu ẹnu atẹ lu Ukraine fun igbiyanju rẹ lati lo awọn ọmọ ilẹ Afrika ninu ogun rẹ pẹlu Russia.