Wọ́n ti kéde ọjọ́ ayẹyẹ ìgbadé Alaafin Oyo tuntun

Aworan Alaafin tuntun pẹlu gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde.

Oríṣun àwòrán, seyi makinde/x

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede wi pe ayẹyẹ ifinijoye fun Alaafin Ọyọ tuntun, Oba Abimbola Akeem Owoade ti o jẹ Alaafin ikẹrindinlaadọta yoo waye niluu Ọyọ lọjọ kẹrin oṣu kẹrin ọdun yii.

Atẹjade ti ijọba ipinlẹ Ọyọ fi ranṣẹ si awọn oniroyin fi idi rẹ mulẹ wi pe wọn ti ṣe ifilọlẹ igbimọ kan ti yoo ṣe alarina laarin Alaafin Ọyọ ati ijọba ipinlẹ Ọyọ fun aṣeyọri ayẹyẹ naa.

Saaju ayẹyẹ ifinijoye naa, Alaafin yoo wa ni ipẹbi fun gbogbo awọn igbesẹ aṣa ati etutu adayeba ki o to gun ori itẹ awọn Babanla rẹ.

Ọjọ Aje, ọjọ kẹtala oṣu kinni ọdun yii ni Alaafin gba ọpa aṣẹ ati iwe ẹri ifinijọye l'ọwọ Gomina Ṣeyi Makinde ni ọfisi rẹ to n bẹ ni agbegbe Agodi niluu Ibadan. Lẹyin igbesẹ yii si ni ijọba kede ọjọ ti ayẹyẹ ifinijoye yoo waye.

Alaafin tuntun, Akeem Owooade

Oríṣun àwòrán, Prince Akeem Owooade/facebook

Láti ìgbà tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti kéde Aláàfin tuntun fún ìlú Oyo ni awuyewuye ti ń wá lórí ìyànsípò Akeem Abimbola Owoade.

Lára àwọn nǹkan tó ń fa awuyewuye náà ni pé gómìnà Seyi Makinde kò tẹ̀lé ìlànà oyè Aláàfin jíjẹ.

Bi Gomina Ọyọ ṣe n sọ pe Itẹ Alaafin ko si fun tita nitori awọn Ọyọmesi ti awọn oiroyin kan jade pe wọn gba owo lọwọ awọn ọmọoye kan to si ni oun yoo fi imu wọn fun fere; lawọn yọmesi kan pẹlu n pariwo pe ohun to wu gomina lo n ṣe pẹlu ọrọ Ọba Alaafin jijẹ.

Bashọrun ilu Ọyọ, Oloye Yusuf Akinade Ayoola, to jẹ olori Ọyọmesi ṣalaye pe o ni ilana ti jijẹ Ọba Alaafin n gba, ṣugbọn ijọba to wa lode bayii ni ipinlẹ Ọyọ ko ṣetan lati tẹle ilana yii.