Ìjọ Àgùdà gba iṣẹ́ lọ́wọ́ Fadá tó lọ ṣe ìgbéyàwó ìdákọ́ńkọ́ pẹ̀lú arẹwà l'Amẹ́ríkà

Aworan Fada naa nibi ayẹyẹ igbeyawo to ṣe naa

Oríṣun àwòrán, Streams of Joy Dallas/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ijọ Aguda lẹkun ilu Warri ni ipinlẹ Delta lorilẹede Naijiria ti jawe lọ rọọkun nile fun Fada kan, Ẹniọwọ Daniel Okanatotor Oghenerukevwe ti wọn fi ẹsun kan pe o lọ ṣe igbeyawo pẹlu obinrin kan ni orilẹede Amẹrika.

Eyi jẹyọ ninu atẹjade kan ti ijọ naa fi sita lọjọ kẹrindinlogun oṣu kinni ọdun 2025, ninu eyi ti wọn ti gba iṣẹ lwọ Fada naa.

Aworan Fada naa nibi ayẹyẹ igbeyawo to ṣe naa

Oríṣun àwòrán, Streams of Joy Dallas/Facebook

Ijọ Aguda naa fi ẹsun kan fada naa ati iyawo rẹ, Dorah Chicah pe wọn ṣe igbeyawo eleyi ti o jẹyọ ninu fọran ori ayelujara kan to jẹ ti ijọ Joy Church ni ilu Dallas lorilẹede Amẹrika ni alẹ ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu kejila, ọdun 2024.

Gẹgẹbi ijọ Aguda ṣe sọ, Fada naa, Ẹniọwọ Oghenerukevwe rọ ij naa ni ọgbọ ọjọ oṣu kọkanla ọdun 2024 lati yọ oun kuro ninu iṣẹ Oluwa gbogbo to lọwọ Fada ninu.

Aworan Fada naa nibi ayẹyẹ igbeyawo to ṣe naa

Oríṣun àwòrán, Streams of Joy Dallas/Facebook

Nitori eyi ni ẹka ijọ naa ṣe rọ ọ pe ko mu gbogbo awọn iwe to niiṣe pẹlu yiyọ orukọ rẹ kuro ninu iwe iṣẹ awọn oluṣọ ninu ijọ Aguda.

Amọ dipo ko mu iwe naa ranṣẹ, igbeyawo rẹ lawọn ri loju opo ayelujara ijọ kan lorilẹede Amẹrika. Eyi lo si sun Biṣọbu ijọ Aguda lẹkun Warri lati paṣẹ ki wọn rọ s loye, ki wọn si gba iṣẹ gbogbo to jẹ mọ iṣẹ alufaa lọwọ rẹ.

Aworan iwe idaduro ti ijọ Aguda kọ fun Fada naa

Oríṣun àwòrán, Catholic Broadcast Commission Nigeria/Facebook