Àwọn ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ayẹyẹ ìbúrawọlé Donald Trump lónìí rèé

Graphic of US capitol
    • Author, Ana Faguy
    • Role, BBC News, Washington
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Oni ọjọ Aje, ogunjọ, oṣu Kinni, ọdun 2025 yii ni Aarẹ Amẹrika tuntun, Donald Trump yoo pada sile ijọba, White House.

Lara ohun ti yoo ṣẹlẹ lọjọ naa ni iburawọle, ayẹyẹ ati idaraya lati owọ awọn olorin atawọn ologun.

Inu iule nla United States Capitol Rotunda ni iburawọlke Trump ati igbakeji rẹ, JD Vance yoo ti waye.

 US Capitol

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ki ni iburawọle naa?

Ọjọ iburawọle ni ọjọ ti saa Aarẹ kan yoo pari ni ọọfisi, ti saa Aarẹ mii yoo si bẹrẹ.

Oun ni ọjọ ipaarọ ijọba to lagbara julọ laarin awọn adari ijọba niluu Washington DC.

Lara ohun ti yoo ṣẹlẹ lọjọ naa ni bi Aarẹ yoo ṣe bura, tabi jẹjẹ nipa aga adari to fẹ joko si.

Bo tilẹ jẹ pe inu oṣu Kọkanla ọdun to kọja ni Trump bori ibo Aarẹ, oni ọjọ Aje ni yoo joko sori aga Aarẹ.

Ṣaaju akoko yii ni Trump ti kọkọ wa nipo naa gẹgẹ bi Aarẹ karundinlaadọta ilẹ Amẹrika laarin ọdun 2017 si 2021 ki Joe Biden to gbajọba.

Oni yii kan naa ni igbakeji Aarẹ, JD Vance yoo ṣe iburawọle pẹlu Trump loju gbogbo aye.

Aworan Capitol builing

Ki ni yoo ṣẹlẹ lasiko iburawọle lonii?

Ile ijọsin St. John, to wa ni Lafayette Sqaure, ni Washington DC ni isin yoo ti kọkọ waye ki wọn to lọ mu tii ni White House.

Awọn olorin yoo ṣere lori papa to wa niwaju ile nla US Capitol ni aago mẹsan an abọ owurọ.

Nibẹ ni wọn yoo ti burawọle fun Trump, ti yoo si sọ awọn iṣẹ akanṣe ti ijọba rẹ yoo ṣe fun ọdun mẹrin to n bọ.

Lẹyin naa, yo wọn inu yara Aarẹ to wa lẹgbẹ ile aṣofin lọ lati tọwọ bọ awọn iwe kan.

Nigba to ba di alẹ, yoo yọju sibi apẹjẹ mẹta ọtọtọ ti wọn gbe kalẹ fun ayẹsi rẹ.

Gẹgẹ bii ọmọlẹyin Kristi, bibeli ni wọn yoo fi burawọle fun Trump.

Lọdun yii, bibeli meji ni Trump yoo fi bura, lara awọn bibeli naa ni eyii ti iya rẹ bun un lọdun 1955, bibeli keji ni eyii ti wọn fi burawọle fun Abraham Lincoln lọdun 1861.

Ni ti JD Vance, bibeli idile rẹ ti iya-iya rẹ fun ni yoo fi bura.

Capitol Rotunda

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Inu ile nla Capitol Rotunda

Nibo ni iburawọle naa yoo ti waye?

Inu ile nla US Capitol ni iburawọle naa yoo ti waye, amọ ẹrọ amohunmawora yoo wa kaakiri ti araalu ti le wo eto naa.

Trump kede loju opo X rẹ lọjọ Ẹti to kọja pe oun n fẹ ki wọn paarọ gbagede naa latari bi oju ọjọ yoo ṣe ri lonii.

Awọn araalu le ma wo bi eto naa yoo ṣe maa lọ ni gbagede Capital One Arena, eyii to le gba eeyan bii 20,000.

O yẹ ki awọn ologun yan fanda, amọ wọn ti wọgile iyanfanda naa latari bi oju ọjọ ṣe ri.

Amọ ṣa, Trump ti ṣeleri lati yọju si awọn eeyan ninu gbagede Capital One Arena naa lẹyin iburawọle rẹ.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti oju ọjọ yoo mu ki wọn ṣayipada gbagede iburawọle.

Lọdun 1985, inu ile ni wọn ti ṣe iburawọle Aarẹ Ronald Reagan nitori otutu to pọ ju lọjọ naa lọhun.

Ronald Reagan ni Capitol Rotunda.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ronald Reagan, 1985.

Awọn wo ni yoo wa nibi iburawọle naa?

Nnkan bii ẹgbẹrun lọna igba eeyan ni ireti wa pe yoo peju siluu Washington lati foju lounjẹ lọjọ naa, ti ọpọ ninu wọn jẹ ololufẹ atawọn alatako Trump.

Bẹẹ naa ni awọn aṣofin ilẹ Amẹrika yoo wa nibẹ to fi mọ Aarẹ to n gbe agbara silẹ, Joe Biden ati igbakeji rẹ, Kamala Harris.

Aarẹ Amẹrika tẹlẹ, Barack Obama ati George Bush yoo wa nikalẹ lọjọ naa pẹlu.

Awọn mii ti a tun gbọ pe yoo wa nibẹ ni awọn baba olowo, Elon Musk, Jeff Bezos ati Mark Zuckerberg

Iroyin ni ọga agba TikTok, Shou Zi Chew ati igbakeji Aarẹ China, Han Zheng yoo wa nibẹ.

Awọn olorin wo ni yoo ṣere?

Obinrin olorin kan to ti gba ami ẹyẹ American Idol, Carrie Underwood yoo ṣere.

Olorin Opera, Christopher Macchio yoo ṣere, ọrẹ tipẹtipẹ Trump, Lee Greenwod, naa yoo tun ṣere nibẹ.

Awọn mi ti yoo tun ṣere ni Kid Rock, Billy Ray Cyrus, Jason Aldean, Rascal Flatts ati Gavin DeGraw.

Awọn kan tun ni olorin takasufe, Nelly wa nibẹ.

Capitol building

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iwaju ile nla Capitol

Bi o ṣe le wo iburawọle naa

Ijọba Amẹrika ti ṣeto tikẹẹti fun awọn ti yoo wa nikalẹ lati wo iburawọle naa niluu Washington.

Ọfe ni awọn tikẹẹti naa amọ o ṣoro lati ri tikẹẹti ọhun gba.

Ṣugbọn fun iwọ gẹgẹ bii ololufẹ BBC o le wo ayẹyẹ naa loju opo ileeṣẹ wa lori ẹrọ amohunmaworan rẹ.

Awọn ti ilẹ Gẹẹsi le wo ni BBC One.