Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Donald Trump yoo bẹrẹ saa keji iṣejọba rẹ gẹgẹ bii aarẹ orilẹede Amẹrika

Lẹyin ti wọn ba ṣeto iburawọle fun un loni ọjọ Aje ni ilu Washimgton DC

Lara awọn awọn ohun ti Trump n gbero lati ṣe lọjọ akọkọ lọọfiisi ni

Fifi opin sawọn to n bimọ l'Amẹrika ki ọmọ wọn le di onilu, ọrọ lori oyun siṣẹ

Kan soju opo BBC Yoruba fun ẹkunrẹrẹ yooku

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Njẹ o mọ iye ti o nilo lati rinrin ajo lọ si Mecca lọdun yii?

Elo lo ba de o?

Alaga ajọ NAHCON to n ri si irinajo lọ silẹ mimọ ni Saudi ti sọ fun BBC pe

Owo to le ni miliọnu mẹjọ naira lawọn Alaaji ati alalaaja kọọkan yoo naa ni Hajj ọdun yii

ọjọ karun un oṣu keji si ni gbedeke sisan owo naa

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Wọn ti yẹ igi fun arakunrin ẹni ọdun mejilelọgọta kan ni China

Ọgbẹni Fan Weiqiu ti wọn yẹgi fun naa wa ọkọ wọ aarin awọn ero to n ṣe are idaraya loṣu kọkanla ọdun to kọja

To si ṣekupa eeyan marundinlogoji

Ni ile ẹjọ ba ni ki oun naa o gbọrun lọ

Aworan Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́