Bíṣọ́ọ́bù tó bá àwọn LGBTQ àti àwọn yòókù bẹ̀bẹ̀ pé kí n ṣàánú fún wọn ní láti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ mi - Trump

Aworan Donald Trump ati Bishop Mariann Edgar Budde

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Fun ọpọ ẹlẹsin Kristẹni, ohun ti Bisọọbu Mariann Edgar Budde sọ nigba to n ba Aarẹ Donald Trump sọrọ ni ile ijọsin pe ko saanu awọn eeyan to n ajọsepọ takọtakọ ati tabotabo tabi awọn eeyan to n yi ara wọn pada ni ko bojumu.

Bakan naa ni awọn mii kan sara pe o iwa olori gidi to fẹran awọn eeyan to n tẹle ni bisọọbu naa se.

Pasitọ kan ṣapejuwe iwa bisọọbu naa gẹgẹ bii eyi to joju ti ni pupọ.

Aarẹ Trump, nigba to n fesi si ọrọ naa lori eto Truth Social ṣapejuwe Bisọọbu gẹgẹ bii eeyan ti ko fẹran Trump.

O wa bẹrẹ pe ko tọrọ aforijin ni itan gbangba.

Ki ni Bisọọbu naa sọ lasiko waasu?

Waasu isẹju mẹdogun naa, Bisọọbu Episcopal ti Washington sọ nipa awọn eeyan ti ẹru n ba bi Trump se wọle aarẹ, awọn eeyan awọn arin irinajo ti ko gba iwe ti wọn to wọ ilu naa ati awọn LGBTQ.

Bisọọbu ni awọn eeyan ni ọja ọla wọn n ba wọn pupọ.

Lati igba ti Trump ti wọle Aarẹ ni o ti bẹrẹ si ma tọwọ bọ awọn iwe aṣẹ, to si jẹ ko di mimọ pe ẹya meji lofin mọ, ọkunrin ati obinrin.

Bakan naa lo kede ofin tuntun ti yoo mu adikun ba bi awọn eeyan se n wọle si orilẹede Amẹrika ni ọna ti ko ba ofin mu.

Bisọọbu Budde, ẹni ọdun marundinlaadọrin, ni o ti figba kan se atilẹyin fun igbayawo tako tako ati tabotabo.

Ki se igba akọkọ ree ti ede ayede yoo waye laarin Bisọọbu naa ati Aarẹ Donald Trump .

Ni saa akọkọ aarẹ, o binu si aarẹ Trump fun aworan kan to ṣapejuwe bi o ṣe mu Bibeli dana nita ile ijọsin St John Episcopal niluu Washington