Lagos City Marathon: Sintayehu Legese láti Ethiopia ló jáwé olúborí

Lagos City Marathon

Oríṣun àwòrán, TWITTER/MYACCESSBANK

Àkọlé àwòrán, Ẹni tó jáwé olúborí lọ́dún tó kọjá,Joshuna Kipkorir ló se ipò kejì ní ipele àwọn okùrin láti ilẹ̀ Ethiopia.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ọmọ ilẹ Ethiopia, Sintayehu Legese lo jawe olubori ninu idije ipinlẹ Eko, Lagos City Marathon pẹlu ẹbun owo $50,000.

Wakati meji, o le isẹju mẹtadinlogun ni ẹni to gbe igba oroke naa lo lati fi sare lati papa isere ti Surulere de Eko Atlantic City.

Bakan naa, Ọmọ Naijiria to kọkọ kọja ori ila, Gideon Goyet yoo gba miliọnu mẹta naira lọ si ile, nigba ti ẹni keji ati ẹni kẹta to jẹ ọmọ Naijiria to kọkọ de ori ila naa yoo gba miliọnu meji ati miliọnu kan lọ sile.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹni to jawe olubori lọdun to kọja, Joshuna Kipkorir lo se ipo keji ni ipele awọn ọkunrin lati ilẹ Ethiopia.

Obinrin akọkọ to kọkọ kọja ori ila ni Meleka Meseret Dinke lati ilẹ Ethiopia bakan naa.