BBC Women's Footballer of the Year 2019: Wo bí o ṣe lè dìbò yan ẹni ti o bá fẹ́

Wọn ti fi orukọ awọn oludije ife ẹyẹ BBC fun agbabọọlu obinrin to pegede ju lọdun 2019 hande o si lee dibo yan ẹni ti o f ko jawe olubori bayii.
Akojọpọ awọn akọṣẹmọṣẹ bii adari ere bọọlu, awọn agbabọọlu, awọn alabojuto ere bọọlu atawọn oniroyin lo yan awọn oludije marun un ti ile iṣẹ BBC yoo gbade fun.
Awọn ti wọn yan naa ni:
- Pernille Harder - Vfl Wolfsburg forward
- Ada Hegerberg - Olympique Lyonnais striker
- Lindsey Horan - Portland Thorns midfielder
- Sam Kerr - Chicago Red Stars and Perth Glory striker
- Saki Kumagai - Olympique Lyonnais defender
Ọjọ keji ọjọbọ oṣu karun ni gbedeke ọjọ ti idibo yoo wa sopin (09:00 BST, 08:00 GMT) ti wn yoo si kede ẹni to ba jawe olubori lọjọ kejilelogun oṣu karun loju opo agbaye BBC World Service ati lori itakun ere idaraya ti BBC, BBC Sport.
Ẹ le tẹ ibi yii lati dibo.
Oun ti ẹ le fẹ mọ sii nipa awọn to n figagbaga ree
Pernille Harder

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọjọ́ orí: 26
Orílẹ̀èdè: Denmark
Iye ìgbà tí ó ṣójú orílẹ̀èdè rẹ̀: 110
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù: VFL Wolfsburg
Ipò: Ọwọ́ iwájú (Forward)
Ada Hegerberg

Oríṣun àwòrán, RONNY HARTMANN
Ọjọ́ orí: 23
Orílẹ̀èdè: Norway
Iye ìgbà tí ó ṣójú orílẹ̀èdè rẹ̀: 66
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù: Olympique Lyonnais
Ipò: Ọwọ́ iwájú (Forward)
Lindsey Horan

Oríṣun àwòrán, MARK RALSTON
Ọjọ́ orí: 24
Orílẹ̀èdè: USA
Iye ìgbà tí ó ṣójú orílẹ̀èdè rẹ̀: 62
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù: Portland Thorns
Ipò: Ọwọ́ àárín (Midfielder)
Sam Kerr

Oríṣun àwòrán, DANIEL POCKETT
Ọjọ́ orí: 25
Orílẹ̀èdè: Australia
Iye ìgbà tí ó ṣójú orílẹ̀èdè rẹ̀: 67
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù: Perth Glory and Chicago Red Stars
Ipò: Ọwọ́ iwájú (Forward)
Saki Kumagai

Oríṣun àwòrán, FRANCK FIFE
Ọjọ́ orí: 28
Orílẹ̀èdè: Japan
Iye ìgbà tí ó ṣójú orílẹ̀èdè rẹ̀: 102
Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù: Olympique Lyonnais
Ipò: Agbá 'wájú ilé mọ́ ọwọ́ ààrín (Defender/defensive midfielder)












