Ọgbà ẹ̀wọ̀n kìí ṣe ilé ìwòsàn alárùn ọpọlọ - Ahmed Ja'afaru ọgbá àgbà ọgbà ẹwọ̀n

Ewon

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Ọgbà ẹ̀wọ̀n kìí ṣe ilé ìwòsàn alárun ọpọlọ - Ahmed Ja'afaru ọgbá àgbà ọgbà ẹwọ̀n

Ọ̀gá àgbà ọgbà ẹ̀wọ̀n orílẹ̀-èdè Nàìjíría Ahmed Ja'afaru ti ṣiṣọ lóju èègun ọ̀rọ̀ pé aláàrùn ọpọlọ mẹ́tàlá ní àwọn ẹbi já jùúlẹ̀ àhá mọ́ àwọn.

O ní àwọn ẹbi oníwá àlùmọ̀kọ́rọ́yín yìí lọ si ilé ẹjọ́ láti lọ gba àṣẹ tí wọ́n fi ni àànfàni lati fi àwọn ènìyàn yìí sẹ́wọ̀n lọ́nà àìtọ́.

Àkọlé fídíò, Mutallab‘s Father: Ọmọ mi ti kábàmọ́ọ̀ ìwà tó wù, ẹ ṣàánú rẹ̀

Lásìkò tó ń ba àwọn oniroyin sọ̀rọ̀ lórí ìwé òfin ọ̀gbà ẹwọ̀n tí ọdun 2019 lọ́nìí, ló ti sàlàyé pé òfin kò fá ààye gba ki wọ́no ma wá jú alárun ọpọlọ sí inú ọgbà ẹ̀wọ̀n kí wọ́n maa ba maa ṣe ojúṣe wọ́n le lóri àti lá bikita fún ọjọ́ orí tàbi àilera wọ́n.

Gẹ́gẹ́ bi o ṣe sọ ipele kẹtala iwé ofin náa fún asoju ọgbà ẹwọ̀n lágbará la'ti kọ ẹnikéni ti o ba ni egbò, tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré ,ẹni ti ó jọ bi ẹni pe kò sí láàye daada tàbi tí o ba ni ààrun ọpọlọ.

O ní ofintuntun yìí yóò ṣegi mọ àwọn òníwa ibàjẹ yìí, bàkan náà ni ayọ yóò wọle to àwọn ẹlẹwan to le ni ẹgbẹ̀run méjì ti wọ́n ti dájọ ikú fún, tí wọ́n si ń wa gbogbo ọ̀nà láti pe ẹjọ kotẹmilọrun to sì ti n ja si pabo, bí ofin náà ṣe yi idájọ ikú náà si ẹwọn gbéré lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá