Port harcourt Bole: Mi kò mọ́ pé bọ̀ọ̀lì títà lè gbé mi dé ipò yìí láyé mi!
O ti le ni ọgbọn ọdun ti mo ti n ta bọọli yii - Grace
Ko si iṣẹ ti eeyan ko le ṣe là ni igbagbọ awọn Yoruba; ẹni to ba jale lo ba ọmọ jẹ.
Oriṣiriṣi ọja ni eeyan le ta, eyi ti orí ba ti pe ni ọna ẹni ni aje fi n ba ni gbe ninu ile.
Grace Osadebe ni yii to n ta bọọli, ẹja ati iṣu sisun ni Pọta to dẹ ti fi ṣe ohun rere gbogbo ti eeyan le fi iṣẹ ọwọ ẹni sẹ.
- Ẹ̀kọ́ mẹ́jọ tó yẹ kí ilẹ̀ Afirika kọ́ lára àjàkálẹ̀ aàrùn coronavirus
- Kìí ṣe gbájúẹ̀ nìkan lọmọ Nàìjá ń ṣe lókè òkun!
- Kíkọ́ ẹ̀kọ́ gboyè nínú iṣẹ́ ìṣègùn ìbílẹ̀ yóò pèsè ìtọ́jú tó péye fọ́mọ Nàìjíríà- Ẹgbẹ́ àwọn dókítà
- Wo àwọn àwòràn tó làmìlaaka nílẹ̀ Adúláwọ̀ lọ́sẹ̀ yìí
- Kí ni ó gbé ọlọ́pàá dé ibi àjọ̀dún ọjọ́ ìbí i Bobrisky?
Damilọla Oduolowu, akọroyin BBC ba Felix, akọbi Madam Grace onibọọli naa sọrọ lori ipa awọn ọmọ naa lati ran iya wọn lọwọ nidi iṣẹ bọọli tita.
Bọọli jẹ ọgẹdẹ agbagba sisun ti awọn eniyan maa n jẹ pẹlu ata dindin tabi ẹpa yiyan.
Grace Osadebe sọ pe ọna ọtọ ti oun fi n dín ata bọọli oun ni wọn fi sọ oun ni inagijẹ Maleesky ni ilu Port Harcourt to jẹ olu ilu ipinlẹ Rivers to ti n mu taje ṣe.
Ajọdun ọdun bọọli maa n waye lẹẹkan lọdun ni ilu Pọta nibi ti gbogbo eniyan a ti ni oore ọfẹ lati jẹ oriṣiriṣi bọọli, ẹja didin, ẹran didin ati ata dindin.