Premier league: Góòlù Sterling tún gbé Manchester city borí Arsenal lẹ́ẹ̀kansi

Oríṣun àwòrán, Premierleague.com
Ija ọga ati ọmọ iṣẹ lo waye lọjọ Satide nigba ti ẹgbẹ agbabọọlu Manchester City gba alejo Arsenal ni papa iṣire Etihad.
Lẹyin ti akọnimọọgba Arsenal, Mikel Arteta fẹyinti gẹgẹ bii agbabọọlu, ọdọ akọnimọọgba Manchester city, Pep Guardiola lo ti kọṣẹ akọnimọọgba ki o to wa gba iṣẹ akọnimọọgba Arsenal.
Eyi mu ki ọpọ maa fi oju ifigagbaga laarin ọga ati ọmọṣẹ wo ifẹsẹwọnsẹ to ba waye laarin wọn.
Nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kẹtalelogun ni Sterling, agbabọọlu Manchester City ṣide goolu ifẹsẹwọnsẹ naa.
Igba keji niyi ti ikọ Arsenal ati Manchester city yoo maa waako lori papa lati igba ti Arteta ti fi Manchester city silẹ wa di ipo akọnimọọgba mu ni ẹgbẹ agbabọọẹu Arsenal.








