Federal Government scholarship 2021/2022: Wo bi o ṣe le fi orúkọ̀ sílẹ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ìjọba Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita fun eto ẹkọ ni Naijiria, Adamu Adamu, ti kesi awọn ọmọ Naijiria to ba nifẹ, to si koju osuwọn, lati fi orukọ silẹ fun eto ẹkọ ọfẹ ijọba apapọ fun ọdun 2021/2022.
Eto ẹkọ ọfẹ naa wa fun awọn to fẹ ẹ kẹkọọ gba oye imọ ijinlẹ akọkọ(undergraduate), ati awọn to ti gba iwe ẹri akọkọ ni awọn orilẹ-ede to ni ajọṣepọ eto ẹkọ pẹlu Naijiria.
Ẹni to ba ri anfaani ẹkọ ọfẹ yii gba yoo ni anfaani lati kẹkọọ gba iwe ẹri akọkọ ni Russia, Morocco, Algeria, Hungary, Egypt, Tunisia, ati Romania.
Fun awọn to fẹ gba iwe ẹri keji ati PHD, wọn le lọ si Russia (iyẹn to ba jẹ nibẹ lo ti gba iwe ẹri akọkọ), China, Hungary, Serbia, ati Mexico.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/NPOWER_NG
Wo bi o ṣe le fi orukọ silẹ
- Gbogbo ẹni to ba koju osuwọn ni lati lọ si oju opo ayelujara ileeṣẹ ijọba apapọ to wa fun eto ẹkọ ni www.education.gov.ng
- Tẹ bọtinni Federal Scholarship Board, to wa ni oju ewe akọkọ
- Ka awọn ilana to wa nibẹ, ki o si fi orukọ silẹ lori fọọmu naa
- Tẹ fọọmu ti o fi ọwọ si jade
- Ranti pe , ọfẹ ni. Ko si olukopa kankan ti yoo san owo fun fọọmu naa tabi lati jẹ anfaani yii.
Ta a lo koju osunwọn?
- Eto ẹkọ imọ ijinlẹ akọkọ (undergraduate)
- Ọjọ ori rẹ gbọdọ wa laarin ọdun mẹtadinlogun si ogun ọdun
- Ẹni to ba fẹ ẹ kopa gbọdọ ni A ati B ninu iṣẹ marun-un ninu idanwo aṣejade nileewe girama
- Imọ Iṣiro ati ede Gẹẹsi gbọdọ wa lara iṣẹ maraarun naa, ati iṣẹ miran to jẹ mọ nkan ti akẹkọọ fẹ ẹ ṣe ni fasiti
- Iwe ẹri naa ko gbọdọ ju ọdun kan meji lọ (2019 si 2020), fun awọn to fẹ ẹ kẹkọọ ni awọn orilẹ-ede ti ko si ni Africa, ati ọdun kan (2020) fun awọn to fẹ ẹ kẹkọọ ni ilẹ Africa.
Ẹkọ ọfẹ fun oye imọ ijinlẹ keji ati PHD
- Fun awọn to fẹ ẹ gba oye keji, ọjọ ori wọn ko gbọdọ ju ọdun marundinlogoji, ati ogoji ọdun fun awọn to fẹ ẹ gba PHD.
- Gbogbo olukopa gbọdọ ni iwe ẹri ipele akọkọ '1st class, tabi ikeji '2nd class Upper Division'.
- Olukopa to ba ti gba ami ẹyẹ ri nilẹ okeere gbọdọ ti ṣiṣẹ ni Naijiria fun ọdun meji
- Gbogbo olukopa ti gbọdọ pari eto isinru ilu, NYSC.
- Ẹri pe ileeṣẹ ti o n ba a ṣiṣẹ yoo yọnda rẹ lati lọ ọ kẹkọọ
Awọn ẹka eto ẹkọ
Imọ ijinlẹ akọkọ 'undergraduate'
•Engineering,
•Geology,
•Agriculture,
•Science,
•Mathematics,
•Languages,
•Environmental sciences,
•Sports, Law,
•Social Sciences,
•Biotechnology,
•Architecture,
•Medicine (perete),
•Pilot Engineering,
•Neurologis.
Imọ ijinlẹ keji ati PHD ni gbogbo ẹka eto ẹkọ
Awọn nkan miran ti olukopa ni lati mọ

Oríṣun àwòrán, TWITTER/FEDERAL MINISTRY OF EDUCATION
Ni wọn igba to jẹ pe awọn orilẹ-ede ti Naijiria ni adehun eto ẹkọ pẹlu kii sọ ede Gẹẹsi, olukopa ni murasilẹ fun ẹkọ ede ilẹ okeere fun ọdun kan gbako ni orilẹ-ede ti wọn ti fẹ ẹ kẹkọọ.
Gbogbo olukopa fun eto ẹkọ imọ ijinlẹ keji ni Russia gbọdọ ti gba iwe ẹri imọ ijinlẹ akọkọ ni Russia, ki wọn si fi si ori ayelujara pẹlu:
a.)Imọ ijinlẹ akọkọ: Esi idanwo WAEC/WASSCE, iwe ẹri ọjọ ori, ati iwe ẹri ilu abinibi
b.)Imọ ijinlẹ keji: Iwe ẹri imọ ijinlẹ akọkọ, iwe ẹri ọjọ ori, WAEC/WASSCE, iwe ẹri ilu abinibi, ati iwe ẹri NYSC.
Awọn olukopa to ba fẹ ẹ kawe ni Hungary le mu to eto ẹkọ meji, bo ba ṣe wu wọn. Wọn si gbọdọ lọ si ori ayelujara www.stipendiumhungaricum.hu , ti ireti wa pe yoo di ṣiṣi silẹ laarin oṣu Kẹwaa si oṣu Kọkanla ọdun 2020, lati fi orukọ silẹ.
Awọn olukopa to ba yege, yoo nilo lati fi ojulowo ẹdà awọn iwe ẹri wọn fun igbimọ to wa fun ẹkọ ọfẹ.
To fi mọ oju ewe akọsilẹ nipa wọn lori iwe irinna wọn, akọsilẹ nipa ilera ara wọn lati ileewosan ijọba, nọmba idanimọ NIN, iwe iyọnda lati ileeṣẹ ọlọpaa,












