Euthanasia in New Zealand: Kìí ṣe New Zealand nìkan ni òfin yìí yóò ti kọ́kọ́ wáye, Canada àti àwọn orílẹ̀-èdè míì rèé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn ènìyàn New Zealand ti dìbò láti sọ ìpolongo pé kí ìjọba gba àwọn ilé ìwòsàn láàyè láti fòpin si ayé aláísàn tó kù díẹ̀ fún láyé rẹ̀ di òfin.
Ọ̀pọ̀ lo pe àṣeyọrí ìdìbò yìí ní ìdìbo fún ojú rere àti ìkáánú nítorí pé, ìdá méjìlélọ́gọ́ta àwọn tó díbò náà ló mú pé kí wọ́n máa ran aláìsàn lọ́wọ́ láti kú, yálà jú kí o máa jẹ ìrora lọ.
Òfin tuntun náà yóò ra àwọn aláìsàn tí wọn kò ni tó oṣù mẹ́fà lọ mọ́ láyé láti gbé ayé láti gba ìrànwọ́ kíkú láì jẹ ìrora níwọ̀n ìgbà tí àwọn dókítà méjì bá ti fọ́wọ́ sí i.
Bákan náà ni àwọn tó dìbò lòdi sí òfin ọ̀hún ni kò ni àwọn ìlànà tó fésẹ̀ múlẹ̀ tó.
- Ẹ gbọ́ ohun tí Desmond Elliot sọ lórí ayélujára tó bí àwọn ọmọ Nàìjíríà nínú
- Àwàdà tàbí óótọ́, kì lò f'ẹkún Kọmíṣọ́nnà ìlera Kogi lórí amóhùnmáwòrán?
- Báyìí ni 50 Kobo ṣe dá ìfẹ̀hónú "Ali Must go" sílẹ̀ tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ lọ
- Ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ déé fáwọn ọmọ Ọlọ́pàá tó kú lásìkò EndSARS, Gómìnà Sanwo-Olu kéde
- Ìjọba Eko kọ orúkọ sí "Palliatives" tiwọn lára o, mo ní ẹrù tèmi f'ọjọ́ ìbí mi tí wọ́n jí - Họ́nọ́rébù Agunbiade
Àbájáde ìdìbò náà ni wọ́n kéde lọ́jọ́ Eti ti ènìyàn tó dín díẹ̀ ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta sì tún di ìbò ọ̀tọ̀ tó fi mọ́ àwọn míràn tó wà ni ilẹ̀ òkèrè, ṣùgbọ́n yóò tó ọjọ́ kẹfa kí wọ́n tó ṣe ikédé àṣeyọri rẹ̀. ṣùgbọ́n kò dájú pé ǹkan yóò yàtọ̀ nítorí àtìlẹyin tó ti ni.
Amúlò òfin náà yóò bẹ̀rẹ̀ láti osù kọkànlá ọdún 2021, èyí yóò sì sọ New Zealand di ọkan lára àwọn ìlú díẹ̀ tí fààyè gbà kí wọ́n ràn èniyàn lọ́wọ́ ikú.

Oríṣun àwòrán, Matt Vikers
Àwọn orílẹ̀-èdè tó tí ń ṣe amúlò òfin yii tẹ́lẹ̀
Belgium
Canada
Colombia
Luxembourg
Switzerland àti Netherlands
Àwọn ìpińlẹ̀ kan náà ni Amẹrika ń ṣee bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ènìyàn Australia ni ìpińlẹ̀ Victoria naa ti sọ di òfin.
Kíni à ń pe ni Euthanasia? Euthanasia jẹ́ ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gba láti ran ẹbí tàbi aláìsàn tí o ni àìsàn tí yóò já sí ikú láàrín oṣù mẹ́fà, ṣùgbọ́n ẹni náà ni ànfani láti yàn pé kí ò n jẹ ìrora títí di ọjọ́ ikú tàbi kí wọ́n fún ni abẹ́rẹ̀ ikú sáájú kí o ma ba rí ìrora.
Àìsàn tí yóò já sí ikú nìkan ni irú òfin yìí wà fún, ó sì yàtọ̀ si ìrànwọ́ láti gbẹ̀mí ara ẹni.













