France Attack: Ọga Ọlọpaa ìlú Nice ní adúnkookòmọ́ni ló gún àwọn èèyàn náà pa

Awọn ọlọpaa niwaju ile ijọsin

Oríṣun àwòrán, EPA

Eeyan mẹta ni Agunbẹ kan kọlu ninu sọọsi kan nilu Nice, lorile-ede Faranse l'ọjọbọ.

Gẹgẹ bi ọga Ọlọpaa ilu Nice, Christian Estrosi ti wi, ikọlu awọn adunkookomọni ni iṣẹlẹ naa, to waye ninu ijọ aguda kan.

Estrosi ni diẹ lo ku ki wọn ge ori baba agba kan, to wa gbadura ja, ti wọn si yinbọn mọ afurasi kan, ki wọn to ti i mọle.

O ni eeyan meji ninu awọn to ku naa ni wọn kọlu ninu sọọsi, ọkùnrin ati obinrin kan ti wọn fi ọbẹ ya ọrun wọn.

Oga ọlọpaa naa ni ṣe ni afurasi naa n pariwo Allahu Akbar kíkankíkan.

Estrosi wa ṣe apejuwe iṣẹlẹ naa bii eyi to farapẹ ikọlu ti wọn ṣe si olukọ kan, Samuel Paty, ti wọn ge lori lẹba ile ẹkọ rẹ lẹyin ilu Paris nibẹrẹ osu yii.

Awọn ọlọpaa niwaju ile ijọsin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bi o tilẹ jẹ pe Ileesẹ ọlọpaa ko ti i daba ohun to le sokunfa ikọlu yii amọ iṣẹlẹ naa lo tẹle ẹhonu to waye lawọn orileede to jẹ ti musulumi.

Iwọde ọhun ni wọn ṣe nitori bi aarẹ Macron ṣe satilẹyin fun atẹjade aworan ẹranko to jọ anabi Muhammed.

Bakanna ni awọn orile-ede kan ti n pe fun didẹyẹ si awọn eroja ti ilẹ Faranse n pese.

Wayi o, ikọlu meji miran lo tun waye laarọ Ọjọbọ nilẹ Faranse ati Saudi Arabia.

Wọn yinbọn pa ọkùnrin kan lẹyin to fi ìbọn ilewọ dunkooko mọ Ọlọpaa, ti wọn si tun kọlu ẹ̀ṣọ́ kan niwaju ile asoju ijọba Faranse to wa nilu Jeddah, nilẹ Saudi Arabia.

Nibayi naa, aarẹ Emmanuel Macron ti gunlẹ si ilu Nice, to si n sepade pẹlu awọn osisẹ Ọlọpaa nibi ti ikọlu naa ti waye.