Wo iye tí bánkì yóò máa yọ lára káàdì ìpè rẹ báyìí, tí o bá lo USSD láti fowó ránṣẹ́ lórí fóònù

Awọn ile ifowopamọ ni Naijiria ti bẹrẹ sii ja owo lati ara kaadi ipe ẹnikẹni to ba n lo USSD code lati fi owo ranṣẹ lori foonu.
Eleyii yii ti bẹrẹ lati ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa ọdun 2025, lẹyin ti ajọ to n mojuto ibaraẹnisọrọ lorilẹede Naijiria, NCC, pa a laṣẹ fun awọn banki lati maa ṣe bẹẹ.
Igbesẹ naa waye lẹyin ọpọlọpọ ijiroro laarin awọn banki ni Naijiria atawọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ lori ẹni ti yoo maa san owo ti wọn maa n ja ti eeyan ba lo USSD Code lati fowo ranṣẹ.
USSD code ni awọn nọmba bii *1234# tabi eyikeyi ti banki yin n lo lati fi ba ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ dowo pọ.
Nigba ti ọrọ naa ko ni ojuutu, ni ajọ NCC kede wi pe lara kaadi ipe onibaara, to ba fowo ranṣẹ ni wọn yoo ti maa ja owo naa bayii.
Ti ẹ o ba gbagbe, ninu apo asunwọn ile ifowopamọ ẹni to ba lo 'code' USSD lati fowo ranṣẹ ni wọn ti maa n yọ owo naa tẹlẹ.
Awọn banki sọ fun awọn onibaara wọn nipa yiyọ owo lati ara kaadi ipe wọn
Lara awọn ile ifowopamọ to ti fi aṣẹ tuntun yii to awọn onibaara wọn l'eti ni awọn banki bii UBA.
Ninu imeeli kan ti banki naa fi ranṣẹ si awọn onibaara rẹ, eyi to tẹ BBC lọwọ, ni wọn ti sọ wi pe ''eyi ti bẹrẹ lati ọjọ kẹta oṣu Kẹfa ọdun 2025 , ati pe lati ọdọ ajọ NCC to n ṣakoso eto ibaraẹnisọrọ ni aṣẹ naa ti wa".
"Lati isisinyi lọ, ninu kaadi ipe ẹni to ba lo USSD lati fowo ranṣẹ ni a o ti maa yọ owo bayii pẹlu aṣẹ to wa lati ọdọ NCC.''
UBA ko ṣai rọ awọn onibaara wọn ti ko ba fẹ lo USSD code lati fowo ranṣẹ lori foonu mọ pe, wọn le maa lo banki ori ayelujara ti wọn n pe ni 'internet banking' tabi ki wọn lo aapu.
Bi wọn ṣe n yọ owo ninu kaadi ipe ree

Bi wọn ṣe n yọ owo lati ara kaadi ipe ẹni to ba fowo ranṣẹ nipaṣẹ USSD ni pe ileeṣẹ ẹro ibaraẹnisọrọ ni yoo yọ N6.98 ti ẹni naa ko ba lo ju iṣẹju meji lọ.
Amọ, ki wọn to yọ owo naa, wọn a kọkọ fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si ẹni to fẹ lo USSD lati fowo ranṣẹ naa bo ya o fara mọ ọ.
Lẹyin ti ẹni naa ba dahun wi pe oun fara mọ ọ ni wọn maa to yọ owo naa lara kaadi ipe.
Nigba naa ni banki yoo ṣeto bi owo naa yoo ṣe de ibi to n lọ.
Nnkan to ṣẹlẹ sẹyin

Oríṣun àwòrán, NCC/X
Fun ọpọ ọdun lawọn eeyan ti maa n lo USSD lati fowo ranṣẹ lori foonu lai lo data tabi foonu nla bii Android.
Ṣugbọn awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ maa sọ pe awọn ile ifowopamọ kii san owo kankan fawọn pẹlu bi wọn ṣe n lo ileeṣẹ awọn fun ilo USSD lati fowo ranṣẹ.
Akọsilẹ fi han pe gbese to to N250bn lawọn banki n jẹ awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ni ipari ọdun 2024.
Ọrọ naa lagbara debi wi pe ajọ NCC fẹ gbe orukọ awọn banki to jẹ gbese naa jade.
Koda, NCC paṣẹ nigba naa pe ki banki mẹsan an to n jẹ awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ ni gbese ma lo ''USSD'' mọ ayafi ti wọn ba san owo ti wọn jẹ.
Ọrọ naa niyanju diẹ loṣu Keji ọdun yii nigba ti ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ MTN ri bii N32bn gba ninu gbese tawọn banki n jẹ wọn, amọ, owo to ku ti wọn o tii san si pọ.
Awọn banki ti rọ awọn onibaara wọn ti ko fẹ lo USSD mọ lati maa lo aapu banki wọn tabi opo ayelujara lati fowo ranṣẹ.
Amọ, fawọn eeyan to wa ni igberiko, eyi tumọ si pe iye owo ti wọn fi n pe naa ni wọn o maa lo lati fowo ranṣẹ bayii pẹlu USSD.















