Èmi àti igbákejì mi yóò sin àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Ondo pẹ̀lú ìbẹ̀rù Ọlọ́run, òtítọ́ inú – Aiyedatiwa

Lukcy Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Ebenezer Adeniyan

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Idunu subu lu ayọ nipinlẹ Ondo loni bi awọn olugbe Ipinlẹ naa ṣe jade ni witiwiti lati sajọyọ Iburawọle Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa ati Igbakeji rẹ Olayide Adelami bi yoo ṣe bẹrẹ saa tuntun ọdun mẹrin loni.

Awọn olugbe Ipinlẹ Ondo dibo yan Gomina Lucky Orimisan Aiyedatiwa ni ọjọ kerindinlogun oṣu kọkanla ọdun 2024.

Eto Iburawọle naa waye ni papa isere ilu Akure lẹyin ti wọn burawọle fun Gomina Aiyedatiwa nibi oṣu mẹrinla sẹyin lẹyin ipapoda Gomina ana nipinlẹ Ondo Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu.

Lasiko to n ba awọn ara ilu sọrọ nibi eto naa Aiyedatiwa sọ pe ni ibamu pẹlu ajọyọ ati agbara ra rẹ ni ibamu pẹlu ofin, ohun daraji awọn ọdaran metadinlogoji.

Aiyedatiwa sọ pe awọn ọdaran naa ni wọn ti lo lara saa to yẹ ki wọn lo loriko ikọnilọgbọn nipinlẹ Ondo ti wọn yoo si maa lọ ile wọn layọ ati alaafia ni kete ti Kọmisọna feto idajọ ati adajọ agba ba pari gbogbo eto lori idariji naa.

Gomina sọ pe asiko ti to lati gbe Ipinlẹ Ondo lọ ipele tio ga. O gboriyin fun awọn adari Ipinlẹ Ondo latẹyin wa fun isẹ takuntakun ti wọn ti gbe ṣe pẹlu ileri pe ohun yoo tẹsiwaju lati mu idagbasoke to yanranti ba Ipinlẹ Ondo.

Bẹẹni O gboriyin fun Gomina ana nipinlẹ yi Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, O sapejuwe rẹ gẹgẹ bi akikanju eniyan ati adari to ni afojusun rere fun Ipinlẹ Ondo ati Naijiria lapapọ.

Àwọn ìlérí tí Gómìnà Lucky Aiyedatiwa ṣe fún àwọn olùgbé ìpínlè Ondo

Lasiko to n ba awọn olugbe Ipinlẹ Ondo sọrọ lori afojusun rẹ fun ọdun mẹrin saa rẹ eyi to gberasọ loni, Gomina Lucky Aiyedatiwa sọpe isejọba rẹ yoo gbajumọ afosun oniga meje to pe ni 'IRỌRUN WA' "OUR EASE".

Aiyedatiwa sọ pe ohun yoo gbajumọ eto igbayegbadun awọn ara ilu papa julọ awọn to ku diẹ ka to fun lawujọ.

Adelami

Oríṣun àwòrán, Ebenezer Adeniyan

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gomina sọ pe isejọba rẹ yoo ba awọn oludokowo ṣiṣẹ papọ lati ri daju pe ala rere awọn adari teleri nipinlẹ Ondo lati jẹ ki Ipinlẹ yi ni ibudoko oju omi wa si imuṣẹ.

O sọ pe ni ibamu pẹlu afojusun oniga meje rẹ, isejọba rẹ yoo gbajumọ eto aabo awọn ara ilu. Aiyedatiwa salaye rẹ pe wọn yoo sagbekale eto lati le jẹ ki awọn ara ilu ni ifọkanbalẹ lori awọn esọ alaabo, ti awọn esọ alaabo yoo si ma ji giri si isẹ wọn lasiko ti rogbodiyan ba suyọ.

Aiyedatiwa tun seleri pe ijọba rẹ yoo se igbe larugẹ eto ọgbin, ti wọn yoo si samulo awọn ohun to sodo si agbegbe ori omi nipinlẹ Ondo, ki ise le wa lọpọ yanturu fun awọn ọdọ nipa agbekale okan-n-jokan ileeṣẹ.

O tun salaye pe eto ilera to yanranti yoo wa fun gbogbo awọn ara ilu, ti wọn yoo si maa se idanilẹkọ ati ilanilọyẹ to yanranti fun gbogbo awọn ara ilu. Aiyedatiwa sọ pe gbogbo eniyan ni yoo lanfaani seto ilera to yanranti.

Gomina tun seleri pe gbogbo olugbe Ipinlẹ Ondo ni yoo lanfaani si ina manamana to duro re, to si salaye pe ijọba rẹ yoo tẹsiwaju lati maa sagbekale Metre lowo ti ko ga ju ara lọ fun awọn ara ilu.

Gomina Aiyedatiwa sọ pe ijọba rẹ yoo tun gbajumọ eto igbayegbadun awọn ara ilu, pẹlu ilẹri pe ohun yo pari gbogbo isẹ akanse to n lọ lọwọ ati awọn eyi ti wọn yoo bẹrẹ laipẹ laarin sa ọdun mẹrin eyi to gberasọ loni.

Awọn eekan ilu to wa nibi iburawọle naa ni, Alaga ẹgbẹ Oṣelu APC lorileede yi Abdullahi Ganduje, Gomina Ipinlẹ Eko, Babajide Sanwoolu, ojugba rẹ nipinlẹ Ekiti Abiodun Oyebanji, Minisita fọrọ abẹle Olubunmi Tunji-Ojo to fi mọ awọn miran.