Wo Aisha Shoneye, akẹkọọ ọmọ ọdun mẹtadinlogun to dari ikọ elere idaraya to gba N100m ẹbun ẹkọ ọfẹ
Ko si ohun ti ọkunrin le se, ti obinrin kankan ko le se, bẹẹ si ni ọmọ ti yoo ba jẹ asamu, kekere ni yoo ti maa jẹnu samu-samu.
Bẹẹ ni ọrọ ri nipa awọn akọni ọmọdebinrin ileẹkọ girama kan nipinlẹ Ondo, ti wọn soriire lati ipasẹ ere idaraya.
Iyalẹnu si lo jẹ pe akẹkọọbinrin akẹẹgbẹ wọn, toun naa n kopa ninu ere idaraya yii, lo jẹ alakoso ikọ elere Football naa, ti wọn n pe ni Captain.
Aisha Shoneye ni orukọ rẹ, ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun to tukọ ẹgbẹ agbabọọlu naa, titi wọn fi se oriire.
Ẹgbẹ agbabọọlu Football naa si lo gba ipo kinni ninu idije ere idaraya naa to waye yika Naijiria eyi to ko ogo ati oriire nla ba ileẹkọ ati awọn akẹkọọ elere idaraya naa.
Nibayi yii, ikọ agbabọọlu Football naa ti jẹ ẹbun ẹkọ ọfẹ ti owo rẹ to Miliọnu lọna ọgọrun Naira.

Mo dupẹ lọwọ iya mi, to gba mi laaye lati se ere idaraya to wu mi, ti a fi jẹ ẹbun ẹkọ ọfẹ N100m – Aisha Shoneye
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ alakoso ikọ agbabọọlu naa sọ pe ere idaraya naa da lori ki awọn maa le ara awọn kiri lori papa bii ẹni pe wọn fẹ ja nnkan gba lọwọ ẹnikan.
Wọn salaye pe aago mẹfa aarọ ni awọn akẹkọ naa maa n bẹrẹ igbaradi wọn lojoojumọ nile ẹkọ wọn.
Amọ aago mẹjọ aarọ si ni igbaradi wọn naa yoo wa sopin lati lọ bẹrẹ eto ẹkọ kikọ ni Kilaasi eyi ti ko jẹ ki ere idaraya naa pa eto ẹkọ kikọ lara.
Aisha sọ pe “Mo dupẹ pupọ lọwọ iya mi, to fun mi laaye lati se ere idaraya to wu mi, eyi to ko oriire ba mi.
A kii ri owo lati na lasiko igbara wa amọ awọn olukọ wa maa n da owo laarin ara wọn lati ra awọn ohun eelo to wulo fun wa fun igbaradi ere idaraya naa.
Ẹni ti mo n wo niwaju mi bii awokọse rere ni Tobi Amusan to maa n sare lori ọdan, mo si fẹ ga julọ ninu ere idaraya.”
Iru ere idaraya wo ni Football yii, ti wọn kii fi ẹsẹ gba a?
Nigba ti BBC Yoruba se abẹwo si ikọ agbabọọlu naa, a gbọ ẹkunrẹrẹ alaye nipa ere idaraya naa.
Football ni wọn pe orukọ ere idaraya naa amọ kii se ere bọọlu alafẹsẹgba nitori ẹsẹ kọ ni wọn fi n gba a.
Olukọ ati ọga ile ẹkọ ti awọn akẹkọọ to gba ipo kinni naa ti wa sọ fun BBC Yoruba pe ere idaray Football naa jẹ ajeji si orilẹede yii, ilẹ Amẹrika si lo ti wa.
“Soccer ni Amẹrika n pe ere idaraya bọọlu alafẹsẹgba lori ọdan amọ ere idaraya tuntun yii, ni wọn n pe ni Football.
Ileesẹ Nigeria-America Flag Football association si lo se agbtẹru idije naa laarin awọn ile ẹkọ.
Wọn fikun pe ilẹ Naijiria ni orilẹede akọkọ nilẹ Afirika ti wọn yoo gbe idije yii wa, osu Kọkanla ọdun 2022 si lo gberasọ nilu Eko.
Football ni ere idaraya yii lootọ amọ wọn kii fi ẹsẹ gba a gẹgẹ bii Soccer.
Wọn maa n le ara wọn kiri bii ere bọọlu lootọ amọ wọn ko gba bọọlu.
Bakan naa ni wọn maa n ju nnkan soke bii Basket Ball amọ ko jọọ rara.
Wọn tun maa n le ara wọn kiri lori papa bii igba ti wọn n gba Rugby amọ kii se Rugby rara.”
Wọn salaye siwaju si pe asia wa lara awọn agbabọọlu naa, ti wọn so mọ wọn lara amọ ko gbọdọ jabọ.
Wọn ni ẹni ti ko ba ni okun ninu, ko le kopa ninu ere idaraya naa, ti wọn si gbọdọ ni ọgbọn ori pupọ.
Awọn obinrin si lo n gba ere idaraya naa ni Naijiria.

"Ọna iwe kọ nikan lọna ti akẹkọ le gba doke, ere idaraya naa dara"
Awọn olukọ ati ọga ile ẹkọ ikọ elere idaraya awọn obinrin naa wa dupẹ pe awọn akẹkọọ naa gba ẹbun ẹkọ ọfẹ ti owo rẹ to ọgọrun miliọnu naira.
Wọn ni owo yii ni yoo ran awọn akẹkọọ yii lọwọ lati ka iwe de ibi to ba wu wọn.
Bakan naa ni wọn salaye pe iwe nikan kọ ni ọna abayọ lati soriire laye amọ ere idaraya naa dara, ọkan si ni yoo ran ekeji lọwọ.
















