Ìdí rèé tí àwọn ènìyaǹ kan kò fi gbàgbọ́ nínú kòkòrò àìfojúrí

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Rachel Schraer
- Role, Health and disinformation reporter
“Láti ọjọ́ pípẹ́ ni mo ti ń wá ọ̀nà àbáyọ sí ètò ìlera dípò lílo oògùn òyìnbó,” èyí ni ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu Veronica Haupt ní ilé rẹ̀ tó wà ní agbègbè Cape Town ní South Africa.
Ó ní àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ lásìkò ìgbà tí àìsàn coronavirus ń jà ràìnràìn ti ń fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbéèrè lọ́kàn òun.
Veronica jẹ́ ènìyàn tó máa ń gba àwọn ènìyàn lámọ́ràn lórí lílo àwọn ohun ìbílẹ̀ fún ètò ìlera èyí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì le má fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀.
Ohun tí ó jẹ Veronica lógún ni wíwà láàyè nínú ìlera tó péye àti kíka àwọn nǹkan nípa àwọn ohun ìwòsàn láì lo àwọn tó jẹ́ ti òyìnbó tàbí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì.
Èyí ló mu bẹ̀rẹ̀ sí ní fura sí àwọn ohun èlò tí wọ́n fi pèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára àti pé wọ́n kàn-án nípá fún àwọn ènìyàn kan láti gbà ní àwọn ibi iṣẹ́ kan.
Níbi yìí ni èrò Veronica ti yàtọ̀ sí ti àwọn ènìyàn mìíràn pàápàá lórí ọ̀rọ̀ ìlera.
Ó ní òun gbàgbọ́ pé irọ́ tí wọ́n ti gbìn sí àwọn ènìyàn lọ́kàn láti ọdún pípẹ́ ni pé àìsàn kan le ran ènìyàn kan láti ara ẹlòmíràn.
Àwọn ikọ̀ kan tí wọ́n ní àwọn kò gbà pé àwọn kòkòrò àìfojúrí ń fa àìsàn, ni wọ́n ní ọ̀pọ̀ ènìyàn lórí Facebook àti Telegram wọn
Òun, àti àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti ń pọ̀ si lórí ayélujára, pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀rí tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbé jáde, wọn ò gbà pé kòkòrò àìfojúrí kan le fa àìsàn.
Ìwádìí fi hàn pé àwọn tó kó ara wọn jọ yìí kò sí ṣaájú ọdún 2020, tó sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà tí àìsàn covid-19 ti bẹ̀rẹ̀.
Àmọ́ kò tán síbẹ̀, ojoojúmọ̀ ni wọ́n ń gbòòrò si tí wọ́n sì ń gbilẹ̀ ní ọdún 2023, ọdún mẹ́tà lẹ́yìn ìgbà tí àìsàn covid-19 gbòde.
Àwọn ikọ̀ kan tí wọ́n ní àwọn kò gbà pé àwọn kòkòrò àìfojúrí ń fa àìsàn ni wọ́n ní ọ̀pọ̀ ènìyàn lórí Facebook àti Telegram, tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yìí sì ni àwọn kò gbà virus wà àti pé àwọn tó gbà pé àwọn kòkòrò yìí ní kò le fa àìsàn.
Lára àwọn nǹkan tí wọ́n ń sọ ni pé ní àárín ọdún 1800, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ilẹ̀ Faransé kan, Antonie Bechamp ní àwọn kòkòrò àìfojúrí kò ní ìpalára tí wọ́n le ṣe fún ènìyàn, tí wọ́n kàn fi wọ́n sínú àwọn ẹ̀yà ara ènìyàn tí kò gbádùn.
Àwọn ènìyàn kò ọ̀rọ̀ Bechamp wọlé nígbà náà àmọ́ àwọn ènìyàn kan lórí ayélujára ti fẹ́ máa lò ó báyìí.
Dókítà Dan Wilson tó jẹ́ onímọ̀ biology, tó sì tún ní ojú òpó lórí YouTube tó ń jẹ́ Debunk the Funk ní àwọn tí kò ní ìgbágbọ́ nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì yìí ni ènìyàn le gbé sípò ìlera.

Oríṣun àwòrán, Debunk the Funk
Ó ní èyí ló jẹ́ wíwa ìlera pípé bóya láti ara oúnjẹ, eré ìdárayá àtàwọn ètò ìlera mìíràn. Ó ní èyí kíkọ àwọn oògùn tó sì ti ń fa onírúurú awuyewuye lórí ayélujára.
Dókítà Wilson ní wíwà nínú ìlera pípé máa ń fún àwọn ènìyàn ní àǹfàní láti sọ̀rọ̀ lórí àwọn àìsàn. Yíyàgò fún àwọn oúnjẹ kan àti pé ènìyàn kò lè bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àìsàn.
Wilson ní kò yẹ kó dá lórí pé àwọn kòkòrò àìfojúrí kò sí ṣùgbọ́n kó dá lórí pé ènìyàn le máa gbé àwọn ìgbé ayé kan láti fi jìnà sí àìsàn.
Ó ní lóòótọ́ ni pé kìí ṣe gbogbo àìsàn ló jẹ́ pé kòkòr]o àìfojúrí ló máa ń fà wọ́n, ìgbé ayé àtàwọn ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ ní àyíká máa ń fa àìlera.
Àmọ́ Veronica gbàgbọ́ pé, láì ní ẹ̀rí kankan, àwọn nǹkan tí kò dára tó ń wọ ara ènìyàn ló máa ń fa àìsàn, tó sì máa ń sọ fún àwọn ènìyàn pé ọwọ́ wọn ni ìlera wọn wà pé kò sí lọ́wọ́ dókítà kankan.
Ikọ̀ àwọn ẹgbẹ́ yìí lórí Facebook ti ní àwọn ènìyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n láàárín ọdún 2019 sí àsìkò yìí.
“Dókítà Wilson ní àwọn tí wọ́n ń sọ pé kò sí kòkòrò àìfojúrí jẹ́ àwọn tí kò ní ìgbàgbọ́ nínú abẹ́rẹ́ àjẹsára ni àti pé ìgbàgbọ́ wọn lórí abẹ́rẹ́ àjẹsára ni wọ́n fẹ́ gbé wọ̀ ọ́.
Ó ní òun ti wọ́ bí ìgbàgbọ́ yìí ṣe bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú nǹkan kékeré kí wọ́n tó máa fẹ̀ ẹ́ lójú.
“A lè mú àwọn kòkòrò yìí kí a fi sára àwọn ẹranko láti mú kí wọ́n ṣe àárẹ́. Bákan náà ni a lè jẹ́ kí ó ran ènìyàn kan sí òmíràn.”
“Àmọ́ pllú gbogbo àwọn ẹ̀rí tó hàn yìí, àwọn kan ṣì gbàgbọ́ pé HIV kò lọ ń fa AIDs tó sì ń jẹ́ nǹkan tó ń bani lẹ́rù.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2020, ààrẹ South Africa ìgbà náà, Thabo Mbeki kò gbà pé HIV ló máa ń fa AIDs.
Ó kọ́kọ́ yarí láti gbà pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ máa lo àwọn oògùn láti dènà kí àìsàn náà máa ràn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àwọn oògùn ni ìgbàgbọ́ wà pé wọ́n ti dẹ́kun iké tó lé ní ẹgbẹ̀rún lanà ọ̀ọ́dúnrún gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí ilé ẹ̀kọ́ gíga Harvard gbé jáde.
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ lórí dídènà HIV ní South Africa ní nǹkan ti yàtọ̀ gidi sí bí ó ṣe wà ní ogún ọdún sẹ́yìn àti àsìkò yìí.
“Mi ò rò pé nǹkan tó dára ni pàápàá lórí àwọn nǹkan tó le dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìlú.”
“A ò fẹ́ kí àwọn ìtàn tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tún padà wáyé.”















