Kàyééfì ńlà! Ìlú kan rèé nípínlẹ̀ Osun tí wọn kò ti gbọdọ̀ sin ajá tàbí jẹ ajá
Bi eeyan ba wọ ilu Ara ni ipinlẹ Ọṣun, eeyan yoo ri oniruuru ẹranko ile bii Ewurẹ, Adiyẹ, tolotolo atawọn ẹranko ile miran. Amọṣa ẹranko ile kan ti ẹ ko le ri ni ilu Ara ni Aja.
Kayefi, ọrọ yii lo mu ki BBC News Yoruba tẹ ọkọ leti lọ si ilu Ara lati beere ki lo ba eyi wa gan?
Ninu ọrọ to ba BBC news Yoruba sọ, Kabiyesi Alara ti ilu Ara, Ọba Olubayọ Oyindapọ ṣalaye pe, gẹgẹbi ilu naa ṣe jẹ ọkan lara awọn ilu iṣẹmbaye ni ilẹ Yoruba, ko si bi eewọ ko ṣe ni si. Ọba Oyindapọ ṣalaye pe bi aja kan ṣe ṣe atọna imoribọ Alara kan lọwọ ibinu Alaafin Ọyọ nigba iwasẹ lo ṣokunfa bi wọn ṣe dẹkun aja sinsin ni ilu naa.
Kabiyesi ni Aja yii pada wa di okuta ti wọn n sin gẹgẹ bi oriṣa ninu ilu naa titi di oni.
O ni lootọ ore ni aja naa ṣe ilu Ara, amọ gẹgẹbi itan ṣe sọ pe awọn araalu ko fi nnkankan lọ ọ gẹgẹbi imọriri ore to ṣe, mu ki aja naa fọhun, eleyii to mu ki gbogbo ilu maa lepa rẹ nigba naa ko to wa parada di okuta.



