Folajimi Oyekunle ẹgbẹ́ PDP wọlé àtúndì ìbò aṣojú-ṣòfin l'Abuja ẹkùn Ibadan North

Aworan Họnọrebu Folajimi Oyekunle

Oríṣun àwòrán, Other

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ eleto idibo INEC ti kede Họnọrebu Folajimi Oyekunle oludije ẹgbẹ oṣelu PDP gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu atundi ibo aṣoju-ṣofin niluu Abuja fun ẹkun ariwa Ibadan.

Ọjọgbọn Abiodun Oluwadare Fasiti UI, to jẹ ọga INEC fun eto idibo naa lo ṣe ikede yii nibi ti wọn ti ko esi ibo jọ nile ẹkọ girama Ikolaba niluu Ibadan lanaa ọjọ Abamẹta ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹjọ yii.

Gẹgẹ bii esi ibo ti INEC kede, Họnọrebu Oyekunle ẹgbẹ PDP ri ibo 18,404, to si la Họnọrebu Adewale Olatunji ẹgbẹ oṣelu APC to ni ibo 8,312 mọlẹ.

Ni bayii, Họnọrebu Oyekunle ni yoo rọpo oloogbe Họnọrebu Musiliu Olaide Akinremi (Jagaban) to ku lọdun 2024 eyi to ṣokunfa atundi ibo to waye.

Ọpọ eeyan lo ti n dunnu si bi Họnọrebu Oyekunle ṣe bori ninu atundi ibo naa, tori igba akọkọ ree ti ẹgbẹ oṣelu PDP yoo wọle ibo aṣoju-ṣofin l'Abuja lẹkun ariwa Ibadan lati ọdun 2011.

Ọgọọrọ awọn ọmọ ẹgbẹ PDP lo n fo fayọ lẹyin ti INEC kede Họnọrebu Oyekunle gẹgẹ bi oludije to jawe olubori ninu eto idibo ọhun.

Wọn ni eyi fi han pe ẹgbẹ ẹgbẹ oṣelu PDP n rinlẹ si i nipinlẹ Oyo.

Nípìńlẹ̀ Ogun, òṣìṣẹ́ INEC méjì wọ gàu pẹ̀lú owó tí wọ́n bá lọ́wọ́ wọn

Ẹwẹ, ni ipinlẹ Ogun, ọwọ ọlọpaa ti ba awọn eeyan meji kan ti wọn jẹ oṣiṣẹ ajọ eleto idibo INEC.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Omolola Odutola, ṣalaye ninu atẹjade to fi sita lọjọ Abamẹta ti atundi ibo waye nipinlẹ naa, pe Ọgbẹni Toryem Joe-Stans ati Arabinrin Mandara Aminat, ti wọn jẹ oṣiṣẹ ajọ INEC pẹlu awọn mi-in ni awọn mu.

Odutola ṣalaye pe nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni ikọ ọlọpaa to n wọde ni Iperu Remo, da ọkọ ayọkẹlẹ Mitsubishi ti nọmba rẹ jẹ LAGOS AKD 887 HT, duro.

Ọgbẹni Toryem Joe-Stans ati Arabinrin Mandara Aminat lo ni wọn wa ninu ọkọ naa pẹlu awakọ to n wa wọn.

Nigba ti wọn yẹ ọkọ naa wo ni wọn ba milionu meji aabọ owo naira nibẹ (₦2,500,000.00) bi Odutola ṣe wi.

Nibi ti wọn ti n fi ọrọ wa awọn eeyan naa lẹnu wo lo ni Joe-Stans Toryem ti jẹwọ, pe otẹẹli kan loun ti gba owo naa lọwọ ọkunrin kan to pe ni "Political Solution."

O ni aṣẹ ọga oun loun si tẹle.

Ṣaa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Ogunlowo, ti paṣẹ pe ki iwadii kikun bẹrẹ lori awọn tọwọ ba naa.

O ni ki wọn fi wọn pamọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeren na bi iwadii ṣe n lọ.