Ìyàwó ajagunfẹ̀yìntì Oladipo Diya ti jẹ Ọlọ́run nípè

Folashade Diya

Oríṣun àwòrán, @AledehLive

Àkọlé àwòrán, Ologbe naa tẹri gbaṣọ lọjọ kejidinlogun, oṣu karun un ọdun 2020

Folashade Diya, to jẹ iyawo gomina ologun ipinlẹ Ogun tẹlẹ, ajagunfẹyinti Oladipo Diya ti jẹ Ọlọrun nipe.

Ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin naa dagbere faye lẹyin aisan ranpẹ.

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina fi lede, o ni oloogbe naa tẹri gbaṣọ lọjọ kejidinlogun, oṣu karun un ọdun 2020.

Atẹjade ọhun ka pe "Pẹlu ibanujẹ ọkan ati ogo fun Ọlọrun ni a fi kede iku Oloye Deborah Folashade Diya, iyawo ajagunfẹyinti Oladipo Diya lẹni ọdun mẹrindinlaadọrin."

O tẹsiwaju pe ologbe naa fi aye rẹ jin fun igbeleke aye ọmọniyan ati iṣẹ Ọlọrun.

Lẹyin naa lo ni aarẹ Buhari gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ologbe ọhun si afẹfẹ rere.

Ajagunfẹyinti Diya ni igbakeji aarẹ ologun ana, ọgagun Sani Abacha ki wọn to fẹsun ifipagbajọba kan an.

Àkọlé fídíò, Restructuring: Àgbékalẹ̀ orílẹ̀èdè Nàìjíríà lọ́wọ́ yìí kò lè fàyè