Yoruba Culture: Kò sí nínú àṣà Yorùbá kí wọ́n tú ọfọ fèèyàn lórí fóònù-Gbenga Adeoye

Obinrin kan n daro pẹlu omije loju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Gbogbo nnkan lo ni ilana ninu aṣa Yoruba ṣugbọn ṣe ẹyin mọ bi Yoruba ti ṣe n tufọ fun eeyan?

A waye iku o si, orun nikan lare mabọ.

Bo ba ṣe wu ki eeyan ko pẹ titi lori erupẹ, lọjọ ọjọ kan ni yoo di ero ọrun.

Ti a ba wa padanu ẹbi tabi ọrẹ bawo ni o ti ṣe yẹ ki a fun iru eeyan bẹẹ ni iro iṣẹlẹ laabi yi ti ko fi ni mu ipalara ba a?

Ẹni to ti ku ti ku; amọ a gbọddu ẹmi ati alaafia ẹni to ṣẹku:

Oloye Adegbenga Akani Adeoye to jẹ Kabiesi Onisọkan, ẹgbẹ isọkan ọmọ Oduduwa ṣalaye fun BBC Yoruba pe nilẹ Yoruba a kii deede tufọ feeyan.

O ni iku jẹ nnkan ti a ko gbọdọ fi ọwọ yẹpẹrẹ mu nipa titu ọfọ tori naa ''aṣamọ ọrọ, owe ati afiwe iṣẹlẹ ni a gbọdọ lo lati fi tufọ''

Àkọlé fídíò, EkitiRapeCastration: ìgbésẹ̀ míì lè dẹ́kun ìwà ìfipábánilòpọ̀

Oloye Adegbenga ni ko ba oju mu ki a maa tufọ fun eeyan lori foonu rara.

Ti a ba fẹ tufọ, a gbọdo wa awọn agbaagba ẹbi ati adugbo silẹ, ki a mu ẹni ti oku ku fun naa wọ iyẹwu, ki a wa maa fi ọgbọn beere nipa ẹni to doloogbe lọwọ ẹni ti ọfọ ṣẹ.

Obinrin kan n daro pẹlu omije loju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oloye Adegbenga ni ko ba oju mu ki a ma tufọ fun eeyan lori foonu rara.

''O le jẹ eeyan meji tabi mẹta ṣugbọn wọn ko gbọdọ maa fi ọgbọn kọkọ beere ọrọ lọwọ ẹni naa ki o ba ma baa lojiji''

Adegbenga ni ti o ba jẹ ẹni to nifura ni yoo ti ma woye pe ki lo mu wọn pe oun ati pe ko ni baa lojiji mọ nigba ti wọn yoo ba fi tufọ naa fun un.

Lẹyin ti ọrọ naa ba ti n wọ ọ lara, a o wa bẹrẹ si ni paṣamọ fun un bi ka maa sọ pe ''eyi ma ga o!'' ''ẹ kuku mọkan naa ni o'' ''Ọlọrun a wa pẹlu yin, a dile mu''

Kini ọgbọn ati oye to wa ninu ki a fi ọgbọn tufọ

Lode oni, awọn ọna ibaraẹnisọrọ ti mu ki awọn eeyan maa fi ọrọ ranṣẹ yala nipa atẹjiṣẹ tabi lori foonu.

Amọ ṣa, Oloye Adegbenga ni ti a ko ba fi oye tufọ, o ṣeeṣe ki oku di meji tori a ko mọ iru ipo ti ẹni ti a ba fẹ tufọ fun le wa.

Àkọlé fídíò, Coronavirus tips: Kìí ṣe gbogbo ìbòmù ló ń dá coronavirus dúró

''Ti o ba jẹ ẹni ti o ni ifunpa to ga ti wọn wa lọ tufọ fun un lojiji, ki ni ẹ lero pe yoo tẹyin rẹ wa ti iru ni yẹn ba lọ daku?''

O kasẹ ọrọ rẹ nilẹ pe, a gbodo rọra tufọ fun iyawo oloogbe tabi ọkọ oloogbe pẹlu afiwe iṣẹlẹ to n muni lọkan le ati suuru.

Àkọlé fídíò, Twin Festival 2019: Ṣé ọbẹ ìlasa àti àmàlà ló ń ṣokùnfà bíbí ìbejì ní ìlú Igboọrà?