Death at Airport: Ọkùnrin kan jáde láyé bó ṣe gba ìròyìn ikú aya rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Arinrinajo kan to fẹ gbera kuro ni Naijiria ni papakọ ofurufu ilu Eko ti fo sanlẹ, to si ku, lẹyin to gba ipe lori ẹrọ alagbeka pe iyawo rẹ jade laye.
Asiko ti wọn n ṣe ayẹwọ fawọn arinrinajo to fẹ lọ soke okun, ni iṣẹlẹ yii waye lopin ọsẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni papakọ ofurufu naa, Joseph Alabi fidi ọrọ yii mulẹ fun BBC pe, kete ti arinrinajo naa daku lawọn sare gbe lọ si ile iwosan ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, to si salaisi.
Gẹgẹ bi Alabi ti sọ, iṣẹlẹ naa waye ni aago marun un abọ irọlẹ, ti dokita Ajayi Olamide to wa ni ile iwosan papakọ ofurufu naa si jẹri si pe arinrinajo naa ti ku.
Wọn ti gbe oku arakunrin naa lọ si ibudo igbokupamọ si ni ile iwosan awọn ọmọ ologun ofurufu.








