NLC Strike: Mínísítà fọ́rọ̀ òṣíṣẹ́ pe ìpàdé àwọn olórí òṣìṣẹ́ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun

Awọn oṣiṣẹ n ṣewọde

Oríṣun àwòrán, AFP

Ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria, NLC ti fun ijọba apapọ ni gbedeke ọjọ mẹrin pere lati fi ṣiṣẹ lori awọn ohun to n beere fun lori atunto ati afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ lorilẹede Naijiria ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu owo oṣu tuntun to kereju fun oṣiṣẹ eleyii ti ijọba ṣẹṣẹ kede.

Ẹgbẹ NLC ṣalaye lọjọ Aiku pe, bi ijọba ko ba tete ṣee, iyanṣẹlodi kale-n-kako yoo waye lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu lẹta kan ti ẹgbẹ oṣiṣẹ kọ si ijọba apapọ, eleyii ti akọwe apapọ rẹ, Emmanuel Ugboaja fọwọ si lo yọju eyi sita to si n rọ awọn alakoso ẹkun ẹgbẹ oṣiṣẹ gbogbo lorilẹede Naijiria lati maa mura silẹ.

Amọṣa, bi awọn iwe iroyin abẹle kan lorilẹede Naijiria ti ṣe gbee sita, minisita fọrọ oṣiṣẹ, Chris Ngige ti n lepa ati pana wahala to ṣeeṣe ko bẹ silẹ lagbo oṣiṣẹ.

Nibayii , Ngige ti pe ipade kan pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ oṣiṣẹ, NLC ati igbimọ to n duna-dura lorukọ oṣiṣẹ Joint National Public Service Negotiating Council (JNPSNC) ni ọjọ Iṣẹgun.

Awọn oluwọde nipa ẹkunwo oṣu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Bakan naa ni gomina Kayọde Fayẹmi to jẹ olori ajs awọn gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria, NGF pẹlu ti rawọ ẹbẹ sawọn oṣiṣẹ lati bu omi suuru mu lori igbesẹ a n yanṣa lodi.

O ni ko yẹ kawọ ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹ da luru pọ mọ ṣapa niap dida ọrọ owo oṣu tuntun to kere ju fun oṣiṣẹ pọ mọ ọrọ ẹkunwo oṣu.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun afikun ida mọkandinlọgbọn owo osu fun awọn oṣiṣẹ alakasọ keje si ikẹrinrinla, ati afikun ida mẹrinlelogun fun awọn oṣiṣẹ alakasọ karundinlogun si ikẹtadinlogun.