Akure okada attack: Ọlọ́kadà tí àwọn afunrasí darandaran ṣá ní òun mọ ọ̀kan lára àwọn tó ṣa òun ní àdá

Àkọlé fídíò, Akure okada attack: Ọlọ́kadà tí àwọn afunrasí darandaran ṣá ní

Bi a ba n wa ọna atijẹ kiri, afi kaa yara maa gbadura ki a maa pade ohun ti yoo jẹ wa o.

Bẹẹ lọrọ ri fun Ọgbẹni James Daniel, ọlọkada kan ni ilu Akurẹ to jade lọ ibi iṣẹ ọkada rẹ ṣugbọn to ba ara rẹ ni ileewosan.

Idi abajọ ni pe, awọn ọkunrin meji kan, gẹgẹ bi James Daniel ṣe sọ, ni wọn da oun duro gẹgẹ bi onibara loju popo lagbegbe Igbatoro nilu Akurẹ pe ki o gbe awọn lori ọkada rẹ de Ibafo ki o si tun gbe awọn pada.

Ọgbẹni James to ni darandaran Fulani lawọn afunrasi naa, ṣalaye pe nigba ti awsn n lọ lori ere ni awọn afunrasi mejeeji naa ys ada ti oun ti wọn ṣa oun lada yannayanna ki wsn to gbe ọkada oun sa lọ

O ṣalaye fawọn oniroyin pe n ṣe ni wọn fi oun silẹ ninu agbara ẹjẹ ni kete ti wọn rii pe oun ti daku ki oun le gba ibẹ dero ọrun.

O ni alaanu eeyan kan to n kọja lọ lo to gbe oun lọ sileewosan.

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ileewosan kan ni ilu Akurẹ ni Ọgbẹni Daniel wa to ti n gba itọju.

Ẹkunrẹrẹ ajọsọ ọrọ pẹlu BBC News Yoruba lori ẹrọ ayelujara lo wa loke iroyin yii.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ?

Amọṣa, nigba ti BBC News Yoruba kan si ileeṣẹ ọẹọpaa ni ipinlẹ Ondo lati mọ bi ọrọ ti jẹ, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nibẹ, ASP Tee Leo-Ikoro ṣalaye pe lootọ ni awọn gbọ si ikọlu naa ti awọn ọtẹlẹmuyẹ si ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ ni pẹrẹu.

Amọṣa, O ni ni iwoye ọlọpaa, kii ṣe awọn fulani darandaran lo ṣe ọṣẹ naa bikoṣe awọn janduku.

O fi kun un pe ko si ẹri kankan lọdọ ọlọpaa to fidi rẹ mulẹ pe awọn darandaran fulani lo kọlu James Daniel, ọlọkada naa.