Man United vs Tottenham: Tottenham ya aṣọ iyì mọ́ Manchester United lára nírọ̀lẹ́ ọ̀jọ́ ìsinmi

Tothemham

Oríṣun àwòrán, EPA

Ọjọ buruku Eṣu gbomi mu lọjọ isinmi ọjọ kẹrin oṣu kẹwaa ọdun 2020 jẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United.

Ijamba ṣe Man United nile wọn lẹyin ti Tottenham wọ wọn ni aṣọ ẹtẹ pẹlu ami ayo mẹfa si ẹyọkan.

Egungun to kọkọ jo iran ni yoo wo gbẹyin ni Tottenham fi ṣe fún Man United lẹyin ti Bruno Fernandez gba goolu akọkọ ninu ifẹsẹwọnsẹ ọhun ṣawọn.

Góòlu mẹfa ọtọtọ ni United fi gba pada lọwọ Tottenham.

Eyi ni igba keji ti Man United yoo fidi rẹmi ni papa isere Old Trafford ni saa bọọlu tuntun yii.

Crystal Palace lo kọkọ lu wọn lalubolẹ mọle tẹlẹ.