A ti mú Ibrahim Abdullahi tó wà nídi ìkọlù sí èrò inú reluwé Kaduna sí Abuja- Ọlọ́pàá

Aworan reluwee ti wọn ṣe ikọlu si

Oríṣun àwòrán, NRC

Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti fidi rẹ mulẹ pe ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin to ṣe ikọlu si ọkọ reluwee to n lọ laarin ipinlẹ Kaduna si Abuja lọdun 2022, nibi ti wọn ti ji ọpọ awọn eeyan gbe.

Agbẹnusọ ọlọpaa agba, Olumuyiwa Adejọbi lo sọ eyi di mimọ lasiko to n fidi iṣẹlọ ọhun mulẹ laipẹ yii.

Olumuyiwa Adejọbi sọ pe Ibrahim Abdullahi lorukọ ọkunrin naa, ati pe Mande ni inagijẹ ti ọpọ awọn eeyan mọ ọn si.

O ni iwadii kikun ti awọn ṣe lo jẹ ki ọwọ tẹ Ibrahim lagbegbe kan to wa nijọba ibilẹ Chikun, ipinlẹ Kaduna.

Siwaju sii lo ni Ibrahim ati ikọ rẹ ni wọn ji awọn akẹkọọ fasiti Greenfield gbe

Ninu ọrọ rẹ, o ni “Lọjọ kejila, oṣu kinni, ọdun 2024, ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri sọrọ ijinigbe lọ mu Mande nitosi afara Rido to wa loju ọna Abuja si Kaduna.”

L’Ọjọbọ, ọsẹ yii ni ileeṣẹ ọlọpaa fi oju Mande ati awọn ti ko din ni ọgbọn miran han, to si ni awọn eeyan naa ni wọn ti n dunkooko mọ awọn arinrin-ajo loju ọna marosẹ Kaduna si Abuja.

O ni bi wọn ṣe n ji awọn arinrin-ajo gbe, naa ni wọn tun n pa wọn danu.

“A ri Mande gẹgẹ bi adari agbebọn to n ṣiṣẹ bii ti Bello Turji ati Dogo Gide”.

Igba akọkọ ree ti ileeṣẹ agbofinro sọ pe ọwọ awọn yoo tẹ afurasi to ni ko ipa ninu ikọlu ọkọ oju irin, eyi ti ijọba appọ sọ pe ko ṣẹyin awọn ikọ Boko Haram.

Lara awọn to sọrọ ni ọsibitu 44 to wa nipinlẹ Kaduna, nibi ti awọn agbebọn ti lọ kọlu awọn eeyan ninu ọkọ reluwe naa sọ pe eeyan meje lo ku.

Bakan naa ni wọn tun jẹ ko di mimọ pe awọn mejilelogun lo fi ara pa yannayanna, to fi mọ igbakeji gomina ana nipinlẹ Zamfara, Alaaji Ibrahim Wakkala.