A ti mọ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa Toheeb Eniafe ní ilé-epo ní Eko- Ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Awenegiemeh Martins/Facebook
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti mọ ọlọpaa to yinbọn pa ọkunrin kan sinu ile-epo NNPC to wa lagbegbe Ọbalende, ati pe iwadii ti n lọ lọwọ.
Bo tilẹ jẹ bi awọn kan ṣe n sọ pe awọn oṣiṣẹ ologun ni ẹni to yinbọn pa ọkunrin naa ti wọn pe orukọ rẹ ni Toheeb Ẹniafẹ, bẹẹ lawọn miran n sọ pe ọlọpaa ni.
Ṣugbọn sibẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin ti fidi rẹ mulẹ pe ọlọpaa ni ẹni naa, ati pe Special Protection Unit (SPU) Base 17 to wa ni Lion Building l’Eko lo ti n ṣiṣẹ.
Hundeyin sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii awọn lati rii pe idajọ ododo fi ẹsẹ mulẹ.
Niṣe ni ariwo ikunlẹ abiyamọ gba ẹnu awọn ara agbegbe Ọbalende l’Ọjọru, ọsẹ yii nigba ti wọn sọ pe oṣiṣẹ eleto aabo kan yinbọn pa Toheeb Ẹniafẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lara awọn ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe awọn ọlọpaa meji kan ni wọn gba ọna ẹburu wa mọto wọnu ile-epo NNPC to wa ni Ọbalende.
Ọkan lara awọn to ba awọon akọroyin sọrọ nibi iṣẹlẹ naa, Idowu ṣalaye pe Toheeb ati awọn eeyan ti to lati ra epo nile-epo naa, ati pe lati bii wakati marun-un le diẹ ni wọn ti n duro lati ra epo nibẹ.
Idowu ni ṣadede lawọn ri mọto awọn ọlọpaa to sare gba ọna ẹburu wọnu ile-epo naa, ti wọn si lawọn to ti n duro tipẹ lati ra epo sare pariwo le wọn lori.
Lara awọn to pariwo naa ni Toheeb wa, ti wọn ni ohun tiẹ lo lọ soke ju, to si loun ko le gba ki wọn fi aṣọ ọlọpaa rẹ awọn jẹ.
Idowu tiẹ tun sọ pe Toheeb ati awọn to wa nibẹ sọ fun awọn ọlọpaa naa lati tẹle ofin ati ilana, gẹgẹ bi iṣẹ agbofinro ti wọn yan laayo.
Ọrọ yii ni Idowu sọ pe o bi ọkan lara awọn ọlọpaa naa ninu, to fi fa ibọn rẹ yọ, to si yin in fun Toheeb.
Loju ẹsẹ nibẹ ni Toheeb ti fidi lelẹ, to si ku.
Idowu sọ pe bi ọlọpaa naa ṣe rii pe Toheeb ti ku, lo ti ba ẹsẹ rẹ sọrọ, ki awọn to wa nibẹ ma ba a dawo bo lati lu.
Obinrin kan, Funmi Aina toun n wa ounjẹ lagbegbe yii ṣalaye ninu ọrọ tiẹ pe “ọlọpaa yii gba Toheeb leti, to si lo sọ pe o tun fi ibinu sọrọ pe ko yẹ ko gba oun leti.
“Ibinu yii ni ọlọpaa naa fi yọ ibọn, ka too mọ ohun to ṣẹlẹ, iro ibọn la gbọ. Igba ti a maa fi gboju soke, a ti ba oku Toheeb nilẹ, ti ọlọpaa yii si salọ.
“Ohun to ṣẹlẹ yii lo bi awọn to wa nibẹ ninu, ti wọn fi dana sun mọto ọlọpaa mejeeji to wa nitosi.”
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ loju opo ayelujara ti X rẹ, agbẹnusọ ọlọpaa, Benjamin Hundeyin sọ pe iwadii ti n lọ lọwọ.
“A ti mọ ẹni to yinbọ naa, ati pe ọkan lara awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ ni Special Protection Unit (SPU) Base 17, Lion Building, l’Eko ni.
“Iwadii ṣi n lọ lọwọ ati pe a maa fi abajade ohun to ṣẹlẹ sita. Ju gbogbo rẹ lọ, ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti n ṣiṣẹ pẹlu mọlẹbi oloogbe naa lati rii pe idajọ ododo waye.”















