Ẹ ṣàwárí àwọn òǹtajà epo tó ń gbé epo pamọ́ - Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin rọ ẹ̀ṣọ́ ààbò

Ile igbimọ aṣoju sofin orilẹede Naijiria ti rọ awọn agbofinro lati ṣawari awọn ontaja epo ti wọn gbe epo pamọ, ki wọn si foju ba ofin.
Igbimọ ile to n risi epo bẹntiroolu labẹ alaga, Ikenga Ugochinyere ati Odianosen Okojie lo parọwa naa lasiko ipade kan ti wọn ṣe ni niluu Abuja.
Ugochiyere ni igbimọ ile ti ṣe ipade pọ pẹlu awọn ontaja epo, ileeṣẹ NNPC ati awọn ajọ mii lori ohun to sẹlẹ nipa ọwọngogo epo.
O ni ọwọngogo epo ni yoo wa fun igba ranpẹ, eyi to ni ohun to ṣokunfa rẹ ni eto irin gbigbe epo wọlẹ ti kudiẹkudiẹ ba ati igbeṣẹ awọn ontaja kan ti wọn gbe epo naa pamọ.
“Lasiko yii, a koroju si igbesẹ awọn eeyan yii ti wọn tori kudiẹ kudiẹ igbe epo ati lati ri pe wọn jere gbe epo pamọ eyi to n fa inira fun ọpọlọpọ araalu.
“A n fi asiko yii kesi awọn agbofinro lati ṣe atilẹyin fun awọn ileeṣẹ NNPC, NMDPRA, PETROAN, NARTO ati awọn ẹka mii lati ri epo wa ni ita fun awọn araalu ati iye owo rẹ ko ga ju ara fun rira.”
Ki lo ti waye ṣaaju lori ọrọ ọwọngogo epo bẹtiroolu?
Bẹrẹ lati olu ilu orilẹede Naijiria lọ si awọn ipinlẹ mii ni awọn araalu ti n la ọpọlọpọ inira kọja lori rira epo bẹtinroolu.
Pupọ awọn Ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu ni o wa ni titi pa niluu Abuja, ti ọpọ awọn osisẹ ijọba ati aladani ni ko anfani lati de si ibi iṣẹ wọn ni aṣiko.
Yatọ si pe ko si epo naa fun awọn araalu lati ra, ọpọ awọn ileeṣẹ to n ta epo bẹntiroolu lọwọlọwọ bayii ni wọn ti gbe owo le owo ti wọn n ta epo naa.
Pupọ awọn olugbe ilu Ibadan ni awọn agbegbe bi Iwo-road, Bodija, Sango, Oojo ati Eleyele ni ọrọ ọwọn gogo ṣe ọpọ ikoba fun.
Ọpọlọpọ awọn ile epo ni awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria lo wa ni titi pa, ti awọn miran si n ta epo naa ni ọwọn gogo.















