Àwọn ẹ̀ṣọ́ aṣọ́bodè pápákọ̀ òfurufú Heathrow ní London daṣẹ́ sílẹ̀ ṣùgbọ́n....

Aworan eso asobode

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ẹṣọ aṣọbode papakọ ofurufu Heathrow niluu London bẹrẹ iyanṣodi ọlọjọ mẹrin lonii ọjọ Aje ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii.

Awọn oṣiṣẹ naa pinnu lati bẹrẹ iyanṣẹlodi yii lati fẹhonu han lori iyipada to fẹ ba bi wọn ṣe n ṣiṣẹ.

Iyanṣẹlodi naa yoo ni ipalara fun lilọ bibọ awọn eeyan ni tamina 2, 3, 4 ati tamina 5 papakọ ofurufu Heathrow.

Ileeṣẹ ijọba UK ti kọminu lori iyanṣẹlodi ọhun, amọ, o ni oun ṣetan lati jiroro pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lati yanju ọrọ naa.

Agbẹnusọ fun papakọ ofurufu Heathrow ni oun faramọ igbesẹ ileeṣẹ ijọba lori ọrọ naa.

Awọn irinajo ọkọ ofurufu yoo maa lọ bi o ti yẹ, amọ, awọn eeyan le maa to lori ila.

Ẹgbẹ oṣiṣẹ PCS ni iyanṣẹlodi yii n waye lori igbesẹ awọn alaṣẹ lati gbaṣẹ lọwọ igba ati aadọta oṣiṣẹ.

Akọwe ẹgbẹ PCS, Fran Heathcote sọ pe "awọn ọmọ ẹgbẹ wa n binu lori bi wọn ṣe fẹ fi ipa gba iṣẹ lọwọ awọn kan lara wa.

Bo tilẹ jẹ pe gbogbo wa kọ ni iṣẹ yoo bọ lọwọ wa, iyipada ti yoo ṣẹlẹ yii yoo ṣakoba fawọn akanda ẹda ninu wa.

O yẹ ki ijọba sa apa rẹ lati ma jẹ ki awọn oṣiṣẹ to ni iriri lẹnu iṣẹ lọ nipa agbekalẹ ọna tuntun ti a o maa gba ṣiṣẹ bayii."

Ẹwẹ, agbẹnusọ ijọba ti sọ pe "ayipada ti yoo ba bi awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu Heathrow yoo ṣe maa ṣiṣẹ wa ni ibamu pẹlu b'awọn oṣiṣẹ papakọ ofurufu mii ṣe n ṣiṣẹ.

A maa sọ ẹkunrẹrẹ ayipada ti yoo ba bi wọn n ṣiṣẹ fun wọn.

Ohun to jẹ wa logun ni eto aabo awọn ibode wa, a ṣi ni eto gidi nilẹ lati ṣe eleyii."