Iná sọ nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́rẹ̀, akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàlá dèrò ọ̀run

China

Oríṣun àwòrán, getty images

Awọn ọmọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ mẹtala ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹsan an si mẹwaa lọ lo ti jade laye bayii lẹyin ti ina kan dede sọ ninu ilegbe wọn to wa ninu ọgba ile ẹkọ kan ni China.

Ile ẹkọ alakọbẹrẹ Yingcai, to wa ni abule Yanshanpu, ni ẹkun Henan ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ijọba ti fi ṣikun ofin mu alaṣẹ ile ẹkọ naa lagbegbe Nanyang bayii, iwadii si ti bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa ina ọhun.

Yatọ si awọn akẹkọọ to jade laye, ẹnikan ti wa nile iwosan nibi to ti n gba itọju, ara rẹ si ti n balẹ.

Ọkan lara awọn olukọ ile ẹkọ naa sọ fun ileeṣẹ iroyin abẹle Hebei Daily pe ipele kẹta ni gbogbo awọn akẹkọọ ti ọrọ naa kan wa.

Akẹkọọ bii ọgbọn lo wa ninu ilegbe naa lasiko ti ina ọhun ṣẹyọ, wọn si doola pupọ ninu wọn lai farapa.

Ileeṣe iroyin abẹle Xinhua jabọ pe gbogbo akoko ti ina naa fi jo ko to wakati kan ki awọn oṣiṣẹ panpana to rẹyin rẹ.

Xinhua jabọ siwaju si pe ile ẹkọ aladani ni ile ẹkọ ọhun, o si ti le ni ọdun mẹwaa ti wọn gbe e kalẹ.

O ni awọn ọjẹwẹwẹ akẹkọọ ‘nursery’ ni wọn ti da pada sile lọdọ awọn obi wọn lẹyin iṣẹlẹ naa.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ina yoo ṣẹyọ nibi ti awọn eeyan n gbe ni China latari ofin to rọ mọ abo ile ti ko rinlẹ to bo ṣe yẹ lorilẹ-ede naa.

Ninu oṣu Kọkanla ọdun to kọja, ina sọ nile kan to wa niluu Luliang, lagbegbe Shanxi, eeyan mẹrindinlọgbọn lo ku nibẹ.

Loṣu kẹrin ọdun kan naa, ina kan to sọ nile iwosan kan ni Beijing mu ẹmi eeyan mọkandinlọgbọn lọ.