Jebba Petrol Tanker Expolsion: Ilé ọgbọ̀n jó ènìyàn mẹ́fà pàdánù ẹmí ní Kwara

Oríṣun àwòrán, KWSG
Ọkọ̀ àjàgbé tó gbé epo bẹtiró ló gbiná ni ìpińlẹ̀ Kwara, ti ènìyàn mẹ́fà pàdánù ẹ̀mí wọ́n nígbà ti ilé tó lé ni ọgbọ̀n jóná lópónà Jebba ni ìjọba ìbílẹ̀ Moro Kwara.
Ìròyìn só pé, ìjánu ọkọ̀ náà lo já ti ọkọ̀ epo tó bọ láti sì ya wọ ààrín bi ti ilé àwọn ènìyàn ń gbé.
Àwọn ti ọ̀rọ̀ náà soju wọn ṣàlàyé pé, ìṣẹ̀lẹ̀ náà já sí ìbúgbàmù ńla lọ́wùrọ̀ ọjọ́rú ti ilé bí ọgbọ̀n sì jóná tó fi mọ àwọn sọ́ọ̀bù ìtajà.

Oríṣun àwòrán, KWSG
Agbẹ̀nusọ àwọn panapana ní ìpínlẹ̀ Kwara Hassan Adekunle ṣàlàyé pé òótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ati pé òótọ́ àti pé àwọn ń gbìyànjú láti kápáa rẹ̀.
Ẹ̀wẹ̀, Ìjọba ìpinlẹ̀ Kwara ti bá àwọn ẹbí àwọn tí ẹ̀mí wọ́n sọnù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹdun.
Gómìnà ni ìbànujẹ́ ní ọ̀rọ̀ náà jẹ fún òun pàápàá jùlọ bí àwọn enìyàn ṣe pàdánù ẹ̀mí wọn ti ọ̀pọ̀ ǹkan okó, ilé ìgbé àwọn ènìyàn sì ṣe ṣègbé.
Ó rọ àwọn ẹbí àwọn olóògbé láti gba fún Ọlọ́rún, bákan náà ló darí àjọ SEMA ti ìpínlẹ̀ náà láti ṣe kíákíá kí wọ́n mọ iyé ǹkan tó bàje kí ìjọba le mọ síi.
Gómínà sọ èyí nínú àtẹjade kan ti agbẹnusọ gómìnà fọ́wọ́ sí, Rafiu Ajakaye, ṣàlàyé pé gomínà tún dari àwọn ilé iṣẹ́ panápaná láti ṣa gbogbo ipá wọn láti pa iná náà.


















