Kí ló ń jẹ́ 'Padding' nilé aṣòfin Nàìjíríà àti àkóbá rẹ̀ lórí ètò ìsúná?

Aworan ibi ti aarẹ Tinubu ti n buwọlu aba iṣuna Naijiria

Oríṣun àwòrán, PRESIDENCY

Ile aṣofin agba Naijiria kede laipẹ yi pe ki Sẹnẹtọ Abdul Ningi to n ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Bauchi lọ rọọkun nile.

Ko si sẹyin ẹsun ti wọn fi kan pe o tabuku ile nipa ẹsun triliọn mẹta Naira to sọ pe wọn ṣe padding rẹ ninu iṣuna ọdun 2024.

Aarẹ ile aṣofin Sẹnẹtọ Godswill Akpabio ṣapejuwe ẹsun yi gẹgẹ bi eleyi to lewu pupọ.

Ọpọ awọn aṣofin ile lo gbe lẹyin aba ti wọn da lati ni ki Ningi lọ rọọkun nile fun oṣu mẹta.

Ẹwẹ, ile aṣofin agba ti tako ọrọ padding yi ti wọn si ni ko si ohun to jọ bẹ ninu iṣuna triliọnu N28.77 triliọnu ti apapọ ile buwọlu.

Nibi ọrọ de duro, Ningi fariga pe oun ko ni ko ọrọ yi jẹ ti o si ni bo ẹ ri loun sọ.

Amọ ki gbogbo rẹ to niyanju, a ni ka beere ka si lara wa lọyẹ pe ki gaan an lo n jẹ padding ati pe ipa wo lo ni lori iṣuna orileede?

Padding ati itumọ rẹ

Ignatius Chukwu to jẹ onimọ nipa ọrọ aje sẹ atupalẹ nkan to n jẹ padding fun wa ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC.

O ni ile aṣofin lẹtọ lati fi kun aba iṣuna orileede nigbakugba ti ẹka apaṣẹ ijọba ba gbe wa siwaju wọn.

O ni ''nkan taa mọ ni pe ti ẹka apaṣẹ ijọba ba gbe aba wa, wọn le ṣe afikun rẹ tabi adinku rẹ lọna ti wọn yoo fi mu anfaani ba ara wọn.''

O fikun pe ti iru owo yi ba wa wọle wọn yoo dari rẹ si ibi ti wọn ti fẹ lo si yatọ si eyi ti ijọba mu wa ba wọn ṣaaju.

Iṣesi yi lo ni wọn n pe ni ''padding'' tabi afikun owo iṣuna ti o wa lori iwe.

''Afikun iṣuna taa mọ si padding jẹ ọna ti wọn yoo fi jẹ ki afojusun iye to wa ninu iṣuna tẹle le ju iye nkan to wa ninu rẹ ṣaaju''

Bẹẹ lo ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin wa.

Ọna ree ti 'padding' fi n ṣe akoba fun orileede

Ignatius to jẹ adari ileeṣẹ iroyin Business Day lẹkun Guusu Guusu sọ pe padding kii ṣe nkan daada ati pe a maa mu aibikita ba eto amulo iṣuna lorileede.

''Ofin to ṣe pataki julọ lorileede lọdọọdun ni aba iṣuna ko si yẹ ki ijọba kankan na owo lai ṣe pe o gba iyọnda igbimọ apapọ ile ti wn si tun gbọdọ tọ pinpin bi wn ṣe na owo yi''

O salaye pe lopin ọdun kọọkan gbogbo owo ti wọn ba na lorukọ ijọba ni wn gbọdọ ṣalaye bi wọn ṣe na.Amọ o ni lori iwe lasan ni alaye yi maa n wa tori pe kii ṣaba waye lawujọ wa.

''Idi ti eyi fi jẹ bẹ ni pe awọn igbimọ alamojuto kọọkan ti ile n gbe kalẹ kii ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ.Bi igba pe wọn n gba abẹtẹlẹ ni wọn ṣe n ṣe iṣẹ yii''

O ni lẹnu kan ki eeyan ṣe padding owo iṣuna ko lorukọ meji ju pe ajẹbanu ni.

Awọn igba miran ti ọrọ padding jẹyọ lagbo oṣelu Naijiria

Aarẹ tẹlẹ Muhammadu Buhari to n ṣe agbekalẹ aba iṣuna niwaju apapọ ile aṣofin

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lọdun 2016,ẹsun ṣiṣe padding iṣuna waye to si tabuku ile aṣofin.

Koda wọn tori rẹ ni ki alaga igbimọ ile to n risi ọrọ eto inawo AbdulMumini Jibrin lọ rọọkun nile logunjọ oṣu Kẹeje ọdun naa.

Jibrin naka alebu si olori ile aṣojuṣofin nigba naa, Yakubu Dogara, ati awọn alaṣẹ ile mẹta mii pe wọn yọ ogoji biliọnu Naira kuro ninu biliọnu ọgọrun owo ti ile ya sọtọ fun inawo ẹkun aṣoju kọọkan.

O ni wọn da owo yi pin laarin ara wọn ni.

Ldun taa n wi yi kanna ni wn ri pe awọn aṣojusofin fọna ẹburu ṣafikun owo biliọnu N480 sinu aba iṣuna ti ẹka apaṣẹ ijọba gbe wa siwaju wọn.

Aṣiri tu nigba ti Minisita feto ilera Isaac Adewole fariga pe kii ṣe aba iṣuna ti ileeṣẹ oun gbe wa siwaju ile ni wọn da pada fun oun.

O ni wọn fi aadọrin biliọnu Naira kun triliọnu Naira mẹjọ le N8.83 trillion toun gbe wa to si di N8.92 trillion.

Bakan naa ni ọdun 2020 aarẹ tẹlẹ Muhammadu Buhari figbe ta lori awọn iṣẹ akanṣe mii ti ile aṣofin gbe wọle sinu aba iṣuna ti wọn si fi le kun iṣuna naa ni iye owo to to N264 billion.

Ninu 2021 nkan taa gbọni pe ile aṣofin fi N500 billion kun owo iṣuna N12.08 trillion ti aarẹ gbe wa siwaju wọn.

Nigba ti wn yoo yẹ wo pada iṣuna naa ti di N13.6 trillion.

Ni 2022 naa aarẹ Buhari loun ri wi pe wọn fi N37.59 bn kun iṣuna ọdun naa gẹgẹ bi owo iṣẹ akanṣe ti wọn.

Ni 2023 bakan naa awọn aṣofin gẹgẹ bi ileeṣẹ aarẹ ṣe sọ tun fi awn akanṣe iṣẹ tuntun N770.72bn sinu iṣuna ti wọn si fi alekun ba owo iṣuna awn ileeṣẹ́ẹ ijọba pẹlu nkan bi N58.55 billion.