Àwọn jàndùkú agbébọn jí èèyàn tó lé ní 50 gbé lọ ní Katsina

Oríṣun àwòrán, Umar Dikko Radda
Eeyan to le ni aadọta ni a gbọ pe awọn janduku agbebọn ti ji gbe lọ ni ijọba ibilẹ Funtua nipinlẹ Katsina.
Awọn olugbe ijọba ibilẹ naa fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ọhun yabo awọn abule kan nibẹ nibi ti wọn ti ji awọn eeyan naa gbe lọ, eyi tawọn ọmọde atawọn obinrin wa ninu wọn.
Bakan naa ni a gbọ pe awọn agbebọn yii ṣeku pa eeyan mẹfa ninu ikọlu mii to waye ni ijọba ibilẹ Dandume ni ipinlẹ kan naa..
Iroyin fi idi rẹ mulẹ pe lọjọ Abamẹta opin ọsẹ to kọja lawọn agbebọn naa yabo agbegbe ọhun, wọn si wa nibẹ titi di ọsan ọjọ keji ti i ṣe ọjọ Aiku.
Malam Ya'u Cibauna to jẹ olugbe ilu Layin Garaa ni ijọba ibilẹ Funtua sọ pe ''ni nnkan bii ago mẹwaa abọ alẹ ni wọn de ti wọn si gbe eeyan mẹtalelaadọta lọ.
Eeyan meji ni wọn pa ni Layin Garaa, mẹrin ni wọn ṣeku pa niluu Mai Kwama nijọba ibilẹ Dandume.''
Olori ilu Layin Garaa, Mustapha Abdullahi, toun naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ sọ pe oniruuru iṣoro lawọn olugbe ilu naa n koju tẹlẹ ki awọn janduku agbebọn to dakun awọn iṣoro naa pẹlu ikọlu ti wọn ṣe.
''Ijọba gan an mọ pe o yẹ ki wọn ṣe iranwọ fun wa lori eto abo to mẹhẹ.
Ko si awọn sọja lagbegbe wa ti wọn le ran wa lọwọ lori ọrọ awọn janduku agbebọn ti wọn n ṣọṣẹ ni ijọba ibilẹ wa.
Awọn ọlọpaa ti wọn wa gan an, wọn o duro niluu wa, ni ṣe ni wọn gba ọdọ wa kọja lọ ilu Garda,'' Abdullahi lo sọ bẹẹ.
Abdullahi ni eto abo to mẹhẹ ti jẹ ki ọpọ olugbe ilu Layin Garaa fi ilu naa silẹ lọ si ibomiran fun abo ara wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ni awọn yoo sọrọ lẹyin ti iwadii lori iṣẹlẹ naa ba pari.
Eto abo to mẹhẹ jẹ ọkan lara iṣoro to n koju ipinlẹ Katsina eyi tawọn olugbe awọn agbegbe tawọn janduku agbebọn ti n ṣọṣẹ ti n rawọ ẹbẹ si ijọba lati wa ojutuu si iṣoro naa.
Ijọba atawọn ẹṣọ eleto abo naa sọ pe awọn ko dẹkun igbiyanju awọn lori ati pese abo to peye fawọn eeyan agbegbe naa.















