Wo aṣọ àwọ̀sùn tó ń pá ẹ̀fọn táwọn onímọ̀ ṣe síta

Ẹfọn ati asọ to n pa ẹfọn

Aisan iba jẹ eleyii to wọpọ ni Naijiria to si ti pa ọpọlọpọ eniyan kaakiri ilẹ Afrika ati ni agbaye.

Eyi ti mu ki awọn onimọ gbiyanju ọpọlọpọ nkan lọna ati gbogun ti aisan iba naa.

A ti ri oriṣirisi aisan iba, tita okun apefọn, ohun ipara to n pa ẹfọn, oogun ẹfọn fifi ati bẹẹ bẹẹ lọ, amọ aisan iba ṣi n pa awọn eniyan lọgọọrọ ni Naijiria.

Eyi lo mu ki awọn onimọ iwadii ni awọn fasiti ni Naijiria tun gbimọ pọ lati wa ọna abayọ si aisan iba pẹlu gbigbe ohun miran jade.

Awọn onimọ lati fasiti Ipinlẹ Kaduna ati ti Fasiti Bingham ti wa pese aṣọ awọsun ti yoo maa dena ẹfọn lasiko ti gbogbo agbaye si n koju aisan iba.

Ajọ Iṣọkan agbaye fi atẹjade lede pe ida marundinlọgọrun eniyan to wa ni ilẹ Afrika ni wọn n koju aisan Iba, paapaa ni ọdun 2021 nikan ṣoṣo.

Aṣaaju ninu awọn oniwadii naa, Ọjọgbọn Zakari Ladan ni aṣọ awọsun naa ni awọn ti pese lati koju ẹfọn, ki wọn maa baa jẹ eniyan mọ.

Zakari fi ogun rẹ gbari pe se ni awọn ẹfọn yoo maa ku ti wọn ba ti n ba le aṣọ naa.

Asọ to n pa ẹfọn

‘’Pẹlu aṣọ yii eniyan ko nilo lati lo oogun ẹfọn miran mọ , ti o ba ti wọ aṣọ apafọn yii ni alẹ.’’

Ọjọgbọn naa ni ọdun 2020 ni awọn ti bẹrẹ si ni ṣiṣẹ lori rẹ lẹyin ti awọn ri owo iranwọ gba lati ṣe iṣẹ naa.

O ni bi aṣọ naa ṣe n ṣiṣẹ ni pe yoo ma fi oorun apakokoro naa sita diẹ diẹ lati inu aṣọ naa

‘’Ti o ba si ti le ẹfọn naa ko si bi o ṣe le jẹ eniyan’’

Amọ ọjọgbọn naa ni ti wọn ba bẹrẹ si ni fọ aṣọ naa agbara rẹ yoo maa dinku.

‘’Bẹẹni wọn le fọ aṣọ naa amọ agbara rẹ yoo ma dinku bi wọn ba ṣe n lo o, o kere tan yoo lo oṣu mẹta ki agbara rẹ to bẹrẹ si ni dinku.’’

Ohun to yẹ ki o mọ nipa aisan Iba

Aisan iba ni o ma n waye lẹyin ti ẹfọn ti wọn n pe ni Anopheles to n gbe aisan iba naa si ara ba ti jẹ eniyan.

Ẹfọn naa lo n gbe aisan yii kiri to ba ti jẹ eniyan paapaa ni alẹ ti awọn eniyan ba n sun.

Ọjọ Karundinlọgbọn, Osu Kẹrin, ọdọọdun ni ayajọ ọjọ igbogunti aisan iba ni agbaye.

Awọn ẹda mẹrin to n fa aisan iba ni P. falciparum, P. malariae, P. ovale ati P. vivax.

Njẹ aisan iba ṣi n pọsi ni Naijiria?

Dokita Usman Qalbusunnah to jẹ onimọ nipa eto ilera ni ileewosan Rigasa ni ipinlẹ Kaduna ni aisan iba ko dinku lorilẹede Niajiria nise lo n pọ si.

‘’O kere tan ni ojumọ ida ọgọts eniyan lo n ni aisan iba, eleyii to fihan pe aisan naa ṣi n goke si.’’

Nkan miran ni pe aisan iba naa n le si lara awọn eniyan nitori awọn oogun ti wọn n lo tako aisan iba naa ko ṣiṣẹ lara awọn eniyan mọ nitori awọn ẹfọn naa n le si ni agbara lara awọn eniyan.

‘’Eyi n mu ki awọn eniyan maa pada si ileewosan lẹyin ọṣẹ kan ti wọn ba ti gbiyanju lati tọju aisan iba nipa lilo oogun oyinbo’’