Gaza: Ẹgbẹ̀rún kan àwọn ọmọdé ni wọ́n ti gé lẹ́sẹ̀ loju ogun

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ibẹrẹ ogun la a mọ, o ṣoro lati mọ igbẹyin ogun. Afẹni ti yoo royin ogun nikan ni ko ni i ku soju ogun.
Akọsilẹ ajọ UNICEF, ṣalaye pe awọn ọmọde ti wọn to ẹgbẹrun kan (1,000) ni wọn ti di ẹlẹsẹ kan bayii.
Wọn ni awọn mi-in ninu wọn ti padanu ẹsẹ mejeeji soju ogun to n ja wọn lati oṣu mẹfa sẹyin.
Pẹlu bawọn ọmọ orilẹ-ede Palestine ṣe n pada si adugbo wọn ni Khan Younis bayii, lẹyin ti awọn ọmọ ogun Isrẹli ko awọn ologun kuro ni Guusu Gaza, awọn kan sọ iriri wọn fun BBC Arabic ninu wọn.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i le fọwọ sọya pe alaafia ti pada jọba tan nile ọhun, sibẹ, wọn n dari pada sile nikọọkan-ejeeji bayii.
Ile ọhun ti dahoro, pupọ wọn ko ribi de si mọ bi wọn ṣe wi.
Awọn mi-in ko tilẹ da ile wọn mọ mọ, gbogbo ohun to duro bii ile tẹlẹ ti di ilẹẹlẹ. Awọn àlàpà ati okuta, titi mọ irin to gbele ro ni wọn n wo nilẹ gelemọ
‘’Aṣọ kan ṣoṣo ni mò ń wọ̀ f’óṣù mèje’’
Ọkunrin Palestine kan, Hamed Yaser Ahmed Abo Hayah, sọ fun BBC Arabic pe,
‘’Mi o le paarọ aṣọ ara mi lati oṣu keje sẹyin. Aṣọ kan ṣoṣo to ku mi ku naa ni mo n wọ kiri.
‘’Ko si nnkan kan fun wa mọ laye. Bi mo ba fẹẹ sun, ṣokoto awọtẹlẹ nikan ni yoo wa nidii mi mọju, ki n le fọṣọ kan ṣoṣo ti mo n wọ kiri to ba dọti’’
Àwọn ọmọ ogun tí wọ́n kúrò ní Gaza lọọ gba agbára sí i ni, ogun ò tí ì tán

Oríṣun àwòrán, Reuters
Atẹjade kan lati ọdọ awọn ologun 98th commando, ṣalaye pe agbo awọn ologun to tadi mẹyin ni Gaza lọọ mu agbara wa ni.
Wọn ni ki i ṣe pe ogun fẹẹ pari ni wọn ṣe kuro.
Wọn ni ikọ alagbara si ṣẹku sibẹ lati da aabo bo ikọ to n ṣoju Isrẹli ni Gaza.
’Ó ti lé lẹ́gbẹ̀rún mẹ́tàlélógún èèyàn tí wọ́n ti pa láàrín oṣù mẹ́fà tí ogun bẹ̀rẹ̀’’

Oríṣun àwòrán, EPA
Akọsilẹ nipa iku awọn eeyan to ti ba ogun yii lọ laarin oṣu mẹfa ti le ni ẹgbẹrun mẹtalelọgbọn (33,000).
Ileeṣẹ to n gbe onka iku naa jade sọ pe 70%, ida aadọrin ni awọn ọmọde atawọn obinrin ti wọn ti pa.
Ajọ kan, ‘Save the children’, sọ pe 13,800 ọmọde ti wọn jẹ ọmọ Palestine ni wọn ti pa ni Gaza.
Awọn to le lẹgbẹrun mejila (12,900) ni wọn si ti farapa.
Ẹgbẹrun kan awọn ọmọde (1,000) ni wọn ti ge lẹsẹ kan abi mejeeji, gẹgẹ bi ajọ UNICEF ṣe sọ.
Eeyan 1.7 million ni wọn ti di alai-nile lori mọ bayii gẹgẹ bi ajọ United Nations ṣe sọ.
Kí lọ ṣẹlẹ̀ lọ́sẹ̀ tó kọjá nínú ogun Isrẹli ati Gaza?
Oṣiṣẹ oluranlọwọ meje padanu ẹmi wọn lẹyin ti wọn ja awọn nnkan iranwọ ti wọn gbe wa si Gaza silẹ.
Isrẹli lo ju ado oloro lu wọn.
Oludasilẹ ileeṣẹ WCK ti wọn pa awọn oṣiṣẹ rẹ yii sọ pe wọn mọ-ọn-mọ pa awọn eeyan oun ni.
O ni eyi to ṣẹlẹ yii ki i ṣe ogun lasan mọ, o ti di ikọju ija si ọmọniyan lai nidii.
Ajeji ni mẹfa ninu awọn eeyan ti wọn pa naa.
Ìpè ati ikilọ ti n lọ sọdọ awọn ologun Isrẹli kaakiri, pe ki wọn dawọ ogun duro.
Ṣugbọn pẹlu bi wọn ṣe lawọn ko ọmọ ogun kuro ni Gaza naa, oju tawọn eeyan fi n wo o ni pe ete ati maa tẹsiwaju ninu ogun naa ni.
Ṣaaju, agbẹnusọ ikọ ologun Isrẹli, Lt Col Peter Lerner, sọ fun BBC pe ikọ̀ awọn kuro ni Khan Younis nitori wọn ti pari iṣẹ nibẹ.
O ni ṣugbọn ogun o ti i pari.
‘’Lootọ ni awọn ọmọ ogun wa ko pọ mọ nibẹ, ṣugbọn iṣẹ ṣi pọ nibẹ ta a maa ṣe.
“ A gbọdọ doju Hamas bole ni gbogbo ibi ti wọn ba wa .

Oríṣun àwòrán, Getty image
Awọn ọmọ Palestine kun fun ireti bi wọn ṣe n pada si Khan Younis
Bi ogun Gaza ṣe wọ oṣu keje to ti bẹrẹ, ireti awọn eeyan Palestine ti wọn le ni miliọnu, n lagbara si i bi wọn ṣe n pada sile wọn ni Ariwa Gaza.
Muhammad al-Mughrabi, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn to wa lati Gaza, sọ pe,
‘’Mo ni ireti, nigba ti mo ri i pe alajọgbele mi naa ti pada sile.
" Loootọ ni wọn ti wo ile mi lulẹ, mo maa ta atibaba sori alapa to ṣeku sibẹ.
‘’Ma a si maa gbe nibẹ tiyi-tẹyẹ, ju ki wọn maa fipa mu mi pe ki n maa gbe lẹkule ileewosan lọ.’’












