Akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Leadcity méjì, ìyàwó ilé àti dẹ́rẹ́bà ọkọ̀ Micra, kú nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ n'Ibadan

Ọkọ Micra to ko ijamba ọkọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ buruku eṣu gbomi mu ni ọjọ́ oni jẹ fáwọn ìdílé kan n'ilu Ibadan torí bí wọn ṣe pàdánù àwọn ẹbí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ kan.

Ijamba ọkọ ti a n wí yìí sí, lọ wáyé ní lagbegbe Soka, lopopona marose ilu Ibadan si Eko niluu Ibadan.

Èèyàn mẹrin sì lọ bá ijamba ọkọ yìí lọ.

BBC de sibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lati ṣe iwadii lori bi ijamba ṣe ṣẹlẹ̀ ati bi o ṣe gba ẹmi eeyan mẹrin lọ.

Iwadii fihan pe aago meje àbọ̀ owurọ oni, ọjọ kẹrinlelogun oṣù kẹfà ni iṣẹlẹ ijamba ọkọ ọhun sẹlẹ niluu Ibadan.

Awọn ti iṣẹlẹ naa waye loju wọn ni eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn lẹsẹkẹsẹ ti ìjàm̀bá ọkọ̀ naa waye.

Ọkọ tirela to kò ijamba ọkọ

Ọkọ tirela kan lo sọ ijanu rẹ nu, to si kọlu ọkọ tirela miran, toun náà sì lọ kọlu ọkọ ayọkẹlẹ Micra to kò èrò - Osojumikoro

Lara awọn to padanu ẹmi wọn ni a ti ri akẹkọọ fasiti Lead City meji, obinrin kan ati dẹrẹba ọkọ.

Oṣojumikoro to ba BBC Yoruba sọrọ ni ọkọ tirela kan lo sọ ijanu rẹ nu, to si kọlu ọkọ tirela miran, ti oun naa wa lopopona ọhun.

Ibrahim Adejumo, ẹni ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ni, ọkọ nla tirela mẹ́rin, ọkọ Micra mẹrin, ati Toyota Camry kan lo kọlu ara wọn nibi ijamba naa,

Adejumo tẹsiwaju pe Akẹ́kọ̀ọ́ meji nile ẹkọ fasiti Lead City, Obinrin kan ati dẹ́rẹ́bà ọkọ ayọkele Micra to rọ lu ọkọ nla náà, lo padanu ẹmi wọn, ti ọkọ ayọkẹlẹ Micra ọhun si bajẹ tan patapata.

Ẹeyan mii to tun ba BBC Yoruba sọrọ, ṣàlàyé pé awọn ara agbegbe naa sare lati doola ẹmi awọn eeyan to wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ Micra to rọ sabẹ ọkọ tirela naa.

Àwọn òṣìṣẹ́ FRSC ń doola ẹmí, wọn sì tún ń lá ọna fáwọn ọkọ láti kọjá

Ere aṣapajude lo mu ki àwọn ọkọ ńlá àti kékeré kọlu ara wọn èyí tó fa ijamba ọkọ to mú ẹmi èèyàn mẹrin lọ - FRSC

Nigba ti oun naa n ba akọroyin BBC Yoruba sọrọ, Ọga agba fun àjọ ẹsọ oju popo ni ìpínlẹ̀ Oyo (FRSC), Rosemary Alo ni ere aṣapajude lo fa a, ti awọn ọkọ naa fi kọlu ara wọn.

O fidi rẹ mulẹ wí pe eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn, ti awọn si ti ko awọn to farapa lọ si ile iwosan Adeoyo to wa ni agbegbe Ringroad niluu Ibadan.

Ajọ ORTMA ati ajọ Road Safety ni wọn jumọ ṣíṣẹ́ lati la ọna fun awọn ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn ko rọna kọja lasiko ti ijamba ọkọ náà waye.