Aráàlú méjì fara gbọta níbi ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìbọn yíyìn iléeṣẹ́ ológun n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT
Ènìyàn méjì ni wọ́n ti gbé dìgbàdìgbà lọ sí ilé ìwòsàn ní agbègbè Odogbo, ìlú Ibadan lẹ́yìn tí wọ́n fara gbọta ìbọn iléeṣẹ́ ológun ní agbègbè náà.
Àwọn ọmọ ogun 2Division tó wà ní agbègbè ọ̀hún tí wọ́n ń ṣe ìdánilẹ̀kọ̀ọ́ ìbọn yíyìn ni ọta ìbọn wọn lọ ba àwọn ènìyàn náà ní ilé wọn.
Nígbà tí wọ́n ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, àwọn ará àdúgbò náà kọminú pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti fa inú fu àyà fu ní agbègbè náà, tó sì ti ń dá ìbẹ̀rùbojo sọ́kàn àwọn ènìyàn.
Àwọn ará àdúgbò ọ̀hún ṣàlàyé pé àwọn ènìyàn méjì tí ọta ìbọn náà bà ni ọmọ ódún mẹ́wàá kan àti bàbá kan tí wọ́n ń pè ní Bàbá Ajeri.
Wọ́n ní lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ní wọ́n ti gbé àwọn méjéèjì lọ sí ilé ìwòsàn tó wà nínú bárékè iléeṣẹ́ ológun náà fún ìtọ́jú.
Wọ́n fi kun pé wọ́n ti rí ọta ìbọn ti ara ọmọ ọdún mẹ́wàá náà yọ ṣùgbọ́n ti bàbá náà àwọn kò ìtíì mọ ohun tó ń sẹlẹ̀ nípa rẹ̀.
Àwọn ara àdúgbò náà ni gbogbo òrùlé ilé àwọn ni ọta ìbọn ti bàjẹ́ tán àti pé ọ̀pọ̀ àwọn ni kò kí lè jáde lásìkò tí àwọn ọmọ ogun náà bá ti bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí.
Ọ̀kan lára àwọn adarí agbègbè náà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní ìbọn tí ọ̀tẹ̀ yìí tún lágbára débi wí pé àwọn ènìyàn kò le wá wọ ilé wọn sùn tó sì jẹ́ wí pé ọ̀nà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbé ọkọ̀ wọn kalẹ̀ sí.
Bákan náà ló ní ẹlòmíràn tó kọ ilé sí agbègbè náà ló ti fi ilé sílẹ̀ láti lọ gbalé sí ibòmíràn nítorí wọ́n ń sá àsálà fún ẹ̀mí wọn.
Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹlòmíràn gan ti ní àìsàn ẹ̀jẹ̀ rúru nítorí ìbẹ̀rùbojo tó ń bá wọn gbé ní gbogbo ìgbà lásìkò tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà bá ti bẹ̀rẹ̀.
Wọ́n wá rọ Ààrẹ Muhammadu Buhari láti báwọn wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa ń wáyé ní lemọ́lemọ́ yìí.















