Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè 286 gba ìwé ìgbélùú gẹ́gẹ́ bí ọmọ Naijiria

Aworan

Oríṣun àwòrán, Presidency

Aarẹ Buhari ti fun awọn ara ilẹ okeere to le ni igba ni iwe igbelu gẹgẹ bi ọmọ Naijiria.

Ilu Abuja ni ayẹyẹ naa ti waye ni Ọjọbọ , Oṣu Kẹsan, ọdun 2022.

Lara awọn to jẹ anfaani yii ni awọn ọmọ ilẹ Lebanọn, Ilẹ Gẹẹsi, Ilẹ Amerika, Egypt, Syria, Italy ati Palestine naa ko gbẹyin ninu wọn.

Aarẹ Buhari sọ fun wọn pe wọn gbọdọ jẹ ọmọ Naijiria rere- ki wọn ba le jẹ anfaani ati ore ọfẹ to wa ni orilẹede Naijiria.

‘’Lẹyin ti ẹ ti jẹwọ ara yin, ti ẹ si jẹjẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria, ẹ gbọdọ fi ifẹ yin han si ilẹ yii.’’

Aworan

Oríṣun àwòrán, Presidency

Aworan

Oríṣun àwòrán, Presidency

Bakan naa ni aarẹ fikun un pe awọn ti wọn lẹtọ si anfaani naa ni wọn jẹ anfaani gẹgẹ bi ọmọ orilẹede Naijiria.

Buhari ni ileeṣẹ to n risi ọrọ abẹle ni Naijiria gbe igbesẹ akọni naa lati fi orukọ wọn ṣọwọ si aarẹ nitori wọn ku ojuwọn nipa igbelarugẹ orilẹede Naijiria.