Àṣà tó burú jáì ni dídénà àwọn obìnrin láti má rí ogún bàbá wọn jẹ- Wike

Oríṣun àwòrán, RVGH Press
Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ti buwọ́lu àbá tó fi ààyè gba ọmọbìnrin láti máa jogún bàbá wọn dòfin.
Òfin yìí yóò fàyè gba àwọnọmọbìnrin láti ní ẹ̀tọ́ sí ogún bàbá wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọkpunrin ní ìpínlẹ̀ náà.
Nígbà tó ń buwọ́lu òfin ọ̀hún, gómínà Wike ní àwọn àṣà kan wà, pàápàá ní ìpínlẹ̀ Rivers tí kò dára tó fún ìdàgbàsókè àwùjọ àti ìbáṣepọ̀ ọmọnìyàn.
Wike ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun wí pé wọ́n dá àwọn obìnrin sí níbi ogun pínpín tó sì jẹ́ wí pá àwọn obìnrin ló wúlọ̀ jùlọ nínú ẹbí.
Ó ní òfin náà wúlò ṣe pàtàkì sí ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Rivers púpọ̀ nítorí yóò fún àwọn obìnrin ní àǹfàní láti máa gba ẹ̀tọ́ wọn.
“Ìdí tí wọ́n fi sọ wí pé èèwọ̀ ni fún obìnrin láti máa jẹ́ nínú ogún tí bàbá rẹ̀ bá fi kalẹ̀ kò yé mi, nítorí pé ènìyàn jẹ́ obìnrin kò ní lẹ́tọ̀ọ́ láti pín nínú ogún bàbá rẹ̀.”
“Kò sí ènìyàn tó yan bóyà ọkùnrin tàbí obìnrin ni òun fẹ́ yà, Ọlọ́run lóhún ṣe é.”

Oríṣun àwòrán, RVGH Press
Gómìnà náà ní ó yẹ kí àwọn ọkùnrin náà máa fi ara wọn sípò àwọn obìnrin nígbà mìíràn tàbí kí wọ́n rò ó wí pé tí Ọlọ́run kò bá fún àwọn ní ọmọkùnrin láyé.
Ó fi kun ṣe yóò dùn mọ́ àwọn ènìyàn tí wọ́n kò bá bí ọmọkùnrin pé kí àwọn jogún gbogbo ohun tí wọ́n bá ní láyé nítorí wọn kò bí ọmọkùnrin.
Wike tẹ̀síwájú pé ìwádìí fi hàn wí pé ọmọbìnrin sábà máa ń wúlò ju ọmọkùnrin lọ fún ẹbí àti pé lọ́pọ̀ ìgbà tí àwọn òbí bá ti darúgbó ọmọbìnrin ló máa ń fi ilé ọkọ wọn sílẹ̀ láti wá tọ́jú òbí wọn.
Bákan náà ló rọ àwọn obìnrin láti má bẹ̀rù gbogbo ìdúnkokò ti wọ́n máa ń rí láti ọ̀dọ̀ àwọn ọkùnrin pàápàá lórí ọ̀rọ̀ ogún pínpín láti àsìkò yìí lọ.
Ó ní gbogbo àwọn obìnrin gbọ́dọ̀ máa dìde láti máa jà fún ẹ̀tọ́ wọn lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin nípa lílo òfin tuntun náà.












