Ọkùnrin tó fẹ́ jí wáyà ká gan mọ iná ní Eko

Ọkùnrin tó gan mọ́ná ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ọkùnrin kan ti ẹnikẹ́ni kò ì tíì mọ ẹyẹ tó ṣu ú báyìí ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ibi tó ti gan mọ́ iná.

Ní agbègbè Isale-Agbede, Lagos Island ní ìpínlẹ̀ Eko ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Keje, ọdún 2022.

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ọkùnrin náà fẹ́ jí wáyà iná ká ní àdúgbò náà ni kí àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná ọba tó mú iná dé ba lẹ́nu ẹ̀ àmọ́ BBC Yorùbá kò ì tíì le fìdí èyí múlẹ̀.

Nínú fọ́nrán kan tó wà lórí ayélujára ṣàfihàn bí òkú ọkùnrin náà ṣe wà láàárín òpó ẹ̀rọ amúnáwá tiransifọ́mà méjì pẹ̀lú àwọn wáyà iná lára rẹ̀.

Àwọn ará àdúgbò náà ní àwọn máa ń rò bóyá àwọn òṣìṣẹ́ iṣẹ́ tó ń pín iná ló máa ń wá jí àwọn ní wáyà ká tí àwọn kò mọ̀ wí pé kìí ṣe àwọn.

Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko, Benjamin Hundeyin ní àwọn kò ì tíì mọ ibi tí ọkùnrin ọ̀hún ti wá.

Hundeyin ní ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan múlẹ̀.