Ọkùnrin ẹni ọdún 66 mórí bọ́ lọ́wọ́ àrùn HIV

Ọkùnrin kan tó ti ń bá àìsàn kògbóògùn HIV fínra láti bíi ọdún 1988 ti mórí bọ́ lọ́wọ́ àìsàn náà.
Àwọn dókítà ní òun ni ẹni kẹrin tó ma bọ́ lọ́wọ́ àìsàn náà.
Ẹnìkan tí àìsàn kògbóògùn náà kò lè mú ló gbà láti fún jẹ́ kí wọ́n ló òun fún ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ inú ẹ̀jẹ̀ tó tún ń bá ọkùnrin náà fínra.
Ní báyìí ọkùnrin náà tí ṣe ìdádúró lílo ògùn HIV.
Ọkùnrin náà tí kò fẹ́ kí àwọn akọ̀ròyìn dárúkọ rẹ̀ ní òun dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run wí pé òun kò ní àìsàn náà mọ́.
Orúkọ ilé ìwòsàn tí wọ́n ti tọ́jú okunrin náà "City of Hope" tó wà ní Duarte, California ni wọ́n fi ń pè é.
Ó ní ó jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu fún òun wí pé òun lè bọ́ lọ́wọ́ àìsàn aṣekúpani èyí tó ti rán ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ òun lọ sí ọ̀run.
Mi ò mọ̀ wí pé ọjọ́ kan le wà tí mi ò ní ní àìsàn kògbóògùn mọ́
Ọkùnrin náà nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní láti ìgbà tí wọ́n ti sọ fún òun wí pé òun ni àìsàn HIV lọ́dún 1988 níṣe ló dàbí wí pé òpin ayé ti dé fún òun ni.
Ó ní òun kò mọ̀ wí pé ọjọ́ kan le wáyé báyìí tí òun kò ní ní àìsàn náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ṣe fún ọkùnrin yìí kìí ṣe láti dènà HIV, ó gbà á kalẹ̀ láti àwọn àìsàn tó ń bá fínra náà.
Dókítà Jana Dicketer ní lẹ́yìn tí à yẹ̀wò àkọ́kọ́ fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọkùnrin ohun kò ní àìsàn yìí mọ́, àwọn fi sí abẹ́ àyẹ̀wò fún oṣù mẹ́tàdínlógún mìíràn kí àwọn tó gbà pé àìsàn náà tí tán lára rẹ̀ pátápátá.
Wọ́n ní àwọn ri dájú pé kò lo ògùn rẹ̀ ní gbogbo àsìkò tó fi wà lábẹ́ àmójútó yìí.

Àwọn mẹ́ta kan ló tí kọ́kọ́ mórí bọ́ lọ́wọ́ HIV
Ní ọdún 2011 ni ẹnìkan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Timothy Ray Brown kọ́kọ́ bọ́ lọ́wọ́ àìsàn yìí.
Dókítà Dickter ní àwọn mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn tí tọ́jú láàárín ọdún mẹ́ta báyìí.
Ó ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé irú iṣẹ́ abẹ tí àwọn ṣe fún ọkùnrin le jẹ́ kí àìsàn HIV lọ, ohun náà ni àwọn kùdìẹ̀kudiẹ tí ó le mú ẹ̀mí àwọn tó ń ṣe é lọ.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Sharon Lewin ni àwọn ènìyàn ń rí ìwòsàn kúrò lọ́wọ́ àrùn náà àti pé ìrètí ṣì wà fún àwọn tó ṣì ń bá àìsàn náà fínra.












