Onírọ́ ni Atiku, gbogbo irọ́ tó pa mọ́ mi ni mà á fèsì sí - Wike

Atiku Abubakar àti Nyesom Wike

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Gómínà ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike ti fèsì sí àwọn awuyewuye tó ń jẹyọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic lásìkò àti lẹ́yìn ètò ìdìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ náà.

Nyesom Wike nígbà tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní pápákọ̀ òfurufú Rivers lẹ́yìn tó dé láti orílẹ̀ èdè Spain ní irọ ló kún gbogbo ọ̀rọ̀ tí olùdíje sípò Ààrẹ ẹgbẹ́ PDP, Atiku Abubakar ń sọ kiri lórí ayélujára.

Ó ní ti àsìkò ọ̀rọ̀ bá ti tó dada òun ma ṣàlàyé bí iṣu ṣe kú àti bí ọ̀bẹ ṣe bẹ́ lórí àwọn ohun tó wáyé nínú ẹgbẹ́ náà lásìkò ètò ìdìbò abẹ́nú náà.

Ó ní ó pọn dandan fún òun láti sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́ gan nítorí tí òun bá kọ̀ láti sọ̀rọ̀, ó ma dàbí wí pé gbogbo irọ́ tí wọ́n ń pa mọ́ òun jẹ́ òótọ́.

Wike ní tí stún bá sọ̀rọ̀, ó pọn dandan kí òsì náà wí ti ẹnu ẹ̀ jáde fáyé àti pé ojoojúmọ̀ ni ọjọ́ orí àwọn ń dàgbà si.

Ó ní ìdí nìyí tí òun ma fi fès]i sí gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n ń fi kan òun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àti pé ó máa jẹ́ ẹ̀rí jẹ́mi nìṣó wí pé òun sọ ipa òun.

Mi ò ṣetán láti fi PDP sílẹ̀ láéláé

Bákan náà ló ní òun pinnu láti dákẹ́ láti ìgbà tí àwọn ti parí ìdìbò abẹ́nú àwọn àmọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP jẹ́ ẹgbẹ́ tí òun ní ìfẹ́ sí.

Wike ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn ń bèrè lọ́wọ́ òun wí pé ṣe òun má fi ẹgbẹ́ PDP sílẹ̀.

Ó fi kun pé gbogbo àwọn ni àwọn jọ ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nítorí náà òun kò ṣetán láti fi ẹgbẹ́ náà kalẹ̀ fún ẹnikẹ́ni.

Ó ní kí àwọn ènìyàn gbàgbé gbogbo àwọn ariwo tí àwọn ènìyàn Atiku ń pa kiri, òun kò ní ohunkóhun láti bá wọn sọ nítorí ariwo ọjà lásán ni wọ́n.

Ó tẹ̀síwájú pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Atiku sọ lórí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ṣe pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ló jẹ́ irọ́ paraku.

Wike fi kun wí pé ó ṣeni láàánú wí pé tí òun kò bá sí láyé ni, gbogbo irọ́ náà ni àwọn ènìyàn kò bá máa gbà ní òótọ́.

Atiku kò rán ẹnikẹ́ni sí mi

Nígbà tó ń fèsì lórí ọ̀rọ̀ wí pé Atiku ni òun ti ń kàn sí Wike fún ìpẹ̀tùsááwọ̀, ó ní kò dára tó wí pé ẹni tó ń wá ipò Ààrẹ Nàìjíríà ń parọ́

“Àwọn sẹ́nétọ̀ kan pè mí wí pé Atiku ní òun rán Saraki sí òun, àma irọ́ ni”

“Mo wà ní Spain, Saraki wá bá mi wí pé báwo la ṣe ma ṣe ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, mo sì bí léèrè wí pé ṣe Atiku ló rán ẹ sí mi, ó ni rárá.”

“Mo ní kí ló fẹ́ ki n ṣe, ó ní òun kò mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ náà le tó báyìí, fún ìdí èyí kò lè ní òun rán ẹnikẹ́ni sí mi.”

Wike fi kun pé tí òun bá ṣetán òun á sọ gbogbo tẹnu òun láìní bìkítà gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn nítorí òun kìí ṣe ẹrú ẹnikẹ́ni.