Kí ló dé táwọn ọmọ South Africa fi ń dà lọ wo 'ọkọ̀ ojú omi àlàáfíà' tó dé láti China?

Oríṣun àwòrán, AFP
- Author, Mohammed Allie
- Role, BBC News, Cape Town
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Otutu to mu lorilẹede South Africa ko ṣe idiwọ fawọn eeyan lati lọ jẹ anfani iwosan ọfẹ eyi ti orilẹede China pese lori ọkọ oju omi niluu Cape Town.
Ọrọ aje South Africa to n ṣojojo ti mu ki ijọba le ma le nawo lori eto ilera daadaa mọ, ọpọ ọmọ orilẹede naa ni ko si lagbara eto iwosan họsibitu aladaani tori bi o ti wọn gogo.
Eeyan to le ni ẹgbẹrun meji ọmọ South Africa lo ti gba iwosan ọfẹ lati igba ti ọkọ oju omi China ti wọn pe orukọ rẹ ni Peace Ark ti de lati ọsẹ to lọ.
Awọn oloyun ti gba itọju nibẹ, bakan naa lawọn mii ti wọn larun oju ti jẹ anfani iṣẹ abẹ ọfẹ.
Ibaṣepọ to dan mọran wa laarin orilẹede South Africa ati China.
Lucy Mnyani sọ fawọn akọroyin wi pe inu oun dun lati ri bi ọmọ to wa ninu iya rẹ ṣe ri fun igba akọkọ.
Mnyani sọ pe oun ti n lọ sile iwosan ti wọn ko si tii fi iru aworan bẹẹ han oun ri.
Ẹlomiran to tun bawọn oniroyin sọrọ, Joseph William, sọ pe lọpọ igba loun ti jokoo fun ọpọ wakati nile iwosan ijọba ki wọn to da oun lohun.
Amọ, o ni ko pẹ rara tawọn eeyan fi n gba itọju nibi eto iwosan ọfẹ ti China gbe kalẹ niluu Cape Town.
Ọkọ oju omi China yii ni awọn oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ nibẹ ṣalaye pe o laye fun itọju ẹẹdẹgbẹrin eeyan lojumọ.
Ọgọrun un eeyan lo wa ninu ọkọ ojum omi yii, eyi ti ọdunrun bẹẹdi wa nibẹ, ogun bẹẹdi lo wa fun awọn alaisan ti ohun to n ṣe wọn lagbara gan an.
Oriṣiiriṣii ile iṣẹ abẹ lo wa ninu ọkọ oju omi yii, koda baalu ẹlikopita fun idoola ẹmi naa wa pẹlu.
Saadiq Kariem to jẹ adari ileeṣẹ eto ilera Western Cape sọ fun BBC wi pe ‘’a ti ṣeto ibi tawọn olugbe ilu Cape Town ti wọn ko nile le duro si ki awọn naa le jẹ anfani eto iwosan ọfẹ yii.
Wọn gbe awọn agbalagba lati ibi ti wọn ti tọju wọn wa fun itọju bakan naa.
Gbogbo akoko ti mo lo bẹrẹ pẹlu fifi orukọ silẹ titi de gbigba itọju ko ju wakati kan lọ.
Nnkan to maa n pẹ ni nile iwosan ijọba tori eeyan maa pọ ju bayii lọ.’’
Ni bayii, eeyan mẹtadinlọgọta ni wọn janfani iṣẹ abẹ ọfẹ.
Dokita Kariem ṣalaye pe pupọ ninu awọn eeyan yii lo ṣe iṣẹ abẹ lori egungun, arun oju atawọn obinrin ti ko fẹ bimọ mọ.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ẹgbẹ oṣelu ANC to n ṣe ijọba ni South Africa ti sọ pe oun yoo pese eto ilera to peye fun araalu nile iwosan ijọba ati ti aladaani.
Minisita eto ilera, Aaron Motsoaledi, sọ pe ijọba yoo si tẹsiwaju pẹlu eto naa bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu ANC kuna lati ni ijokoo to pọ julọ nile igbimọ aṣofin agba orilẹede South Africa ninu eto ibo to waye loṣu Karun un ọdun yii.
Lara awọn nnkan to n kọ awọn eeyan lominu ni pe ẹgbẹ oṣelu DA ti ANC darapọ mọ lasiko idibo tako eto ilera ti ijọba ANC fẹ ṣe yii.
Ọpọ ileeṣẹ eto ilera lo tako eto naa tori wọn gbagbọ wi pe ko ni jẹ kawọn eeyan le maa ṣe eto ilera aladaani fun ara wọn.
Ni bayii, ida 14% awọn eeyan orilẹede South Africa lo wa lori eto ilera aladaani nigba ti ida 86% yoku wa lori eto ilera ijọba eyi ọrun ti n wọ bayii.
Lọsẹ to lọ yii ni ẹgbẹ awọn oniṣowo ati ajọ oṣiṣẹ eleto ilera kọ lati buwọlu adehun kan pẹlu South Africa eyi to n ṣalaye bi ẹlẹkajẹka yoo ti koju ipenija eto ilera lọdun to n bọ.
Awọn ajọ mejeeji to n ṣoju awọn oniṣowo aladaani ati ẹgbẹrun mejila dokita ni inu wọn ko dun eto ilera ijọba NHI pẹlu bi o ṣe wa bayii.
Dokita Manjra sọ iwa ibajẹ ni South Africa ni ko ni jẹ ki eto naa kẹsẹjari.

Oríṣun àwòrán, AFP
Siphiwe Dlamini to jẹ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọmogun South Africa sọ fun BBC wi pe ọpọ eeyan lo ti n jẹ anfani iwosan ọfẹ lori ọkọ oju omi Peace Ark lati igba to ti de silu Cape Town.
Ni Ọjọbọ ni ọkọ oju omi yii yoo kuro niluu Cape Town ti yoo si morile orilẹede Angola ki o to maa lọ sawọn orilẹede mii bakan naa.
Ọkọ oju omi yii ti lọ sawọn orilẹede bii Seychelles, Tanzania, Madagascar ati Mozambique.
Orilẹede China n ṣe eyi lati ni ipa sii lawọn orilẹede Afirika.
Fun bii ogun ọdun bayii ni eto okowo China nilẹ Afirika ti gberu si – bi wọn ṣe n kọ oriṣiiriṣii nnkan bi ile ati ọna ni wọn tun n kọ papa iṣere nla nla kaakiri ilẹ Afirika.















