Àgbàrá òjò wó ilé mẹ́jọ ní Bornu, gbé èèyàn 23 lọ ní Adamawa, ọ̀pọ̀ di aláìnílélórí

Agbara ojo ni Adamawa

Oríṣun àwòrán, Ahmadu Umaru Fintiri

Àkọlé àwòrán, Agbara ojo ni Adamawa
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

O kere tan, ile mẹjọ lo ti wo lulẹ lẹyin agbara omi to tẹlẹ ojo to rọ fun ọpọ wakati niluu Maiduguri, to jẹ olu ilu ipinlẹ Borno.

Iroyin ni nnkan bii aago mẹfa kọja iṣẹju diẹ laarọ ana Ọjọru ni ojo naa bẹrẹ to si rọ fun odidi wakati mẹta gbako, eyii to sọ ọpọ eeyan di alainilelori lawọn agbegbe bii Bulumkutu, Abuja, Moduganari, Ngomari atawọn agbegbe mii to sunmọ omi.

Ẹnikan to n gbe lagbegbe Bulumkutu, Ahmodu Ibrahim, sọ fun awọn akọroyin pe agbara ojo wọ inu ile oun ni nnkan bii aago mẹjọ aarọ ki oun to ko awọn mọlẹbi oun jade kuro nibẹ.

Ẹkun omi

Oríṣun àwòrán, Ahmadu Umaru Fintiri

"Gbogbo ọja to wa ninu sọọbu mi ni omi gbe lọ"

O ni "mo ri ti omi bẹrẹ si n wọle lẹyin wakati kan ti ojo bẹrẹ, mo sare ko awọn ọmọ mi jade lọ sibi ti ko si agbara omi."

Ẹlomiran to ni ṣọọbu lagbegbe ọhun sọ pe gbogbo ọja oun ni omi gbe lọ.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ti kede pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati doola gbogbo awọn ti ọrọ naa kan gbọngbọn.

Alukoro ileeṣẹ naa, ASP Nahum Daso ni lootọ ni agbara ojo naa wo ile mẹjọ palẹ.

Daso sọ pe "lẹyin ojo arọrọda to waye ni Maiduguri, Gomari, Bulumkutu, Jidari, ITE atawọn agbegbe mii, ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iṣẹ idoola awọn ti ọrọ kan.

"O ṣeni laanu pe ile mẹjọ lo ba agbara ojo naa lọ amọ ẹmi ẹnikankan ko sọnu.

"Lati dena riru ofin, a ti ko awọn ọlọpaa si awọn agbegbe to ṣe koko lati daabo bo awọn dukia awọn eeyan lati dena awọn kọlọrọsi to le fẹ lọ ko dukia awọn to fi ile wọn silẹ.

Agbara ojo gbe eeyan mẹtalelogun lọ ni Adamawa

O kere tan, eeyan mẹtalelogun ni ẹmi wọn sọnu ninu agbara omi to waye nipinlẹ Adamawa, ti ọpọ awọn mii si farapa.

Agbara ọhun waye lẹyin ti ojo rọ lati afẹmọju ọjọ Abamẹta titi di aarọ ọjọ Aiku.

Gomina ipinlẹ naa, Ahmadu Fintiri sọ pe yatọ si awọn mẹtalelogun to ku, ọpọ eeyan lawọn ṣi n wa.

Nigba to n ba awọn ti iṣẹlẹ naa sọ di alairilegbe sọrọ, o ni iṣẹlẹ ọhun fa oun lọkan ya, o si ba inu oun jẹ gidi.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ile ti awọn eeyan n kọ si oju ọna to yẹ ki omi maa gba kọja lo ṣokunfa awọn iṣẹlẹ omiyale to n waye nibẹ.

O ni "ti a ko ba wa ojutu si bi omi ṣe n ya wọ ilu wa, iya yii yoo tẹsiwaju lati maa jẹ wa lọdọdun.

Amọ ṣa, akoko yii kii ṣe akoko lati da ẹnikẹni lẹbi, o jẹ akoko lati gbẹ awọn gọta ti omi yoo maa gba kọja."

Iṣẹlẹ omiyale to mi Naijiria titi ni 2025

Ipinlẹ Niger

Ni ipari oṣu Karun un, ọdun 2025 yii ni iṣẹlẹ omiyale kan kọlu ilu Mokwa, nipinlẹ Niger, eyii to mu ẹmi eeyan to le lọgọrun un lọ.

Yato si eeyan bii 151 to ku nibẹ, eeyan bii mejidinlọgọrun un lo di awati gẹgẹ bii ijọba ṣe sọ amọ awọn eeyan agbegbe ọhun sọ pe iye eeyan ti ijọba kede kere ju iye awọn ti ọrọ naa kan lọ.

Ṣaaju iṣẹlẹ yii ni iṣẹlẹ omiyale kan ti kọkọ waye latari adagun odo Jebba Hydroelectric Dam ti wọn ṣi silẹ, eyii to wọ ilẹ oko bii ẹgbẹrun marun un lọ lawọn ilu bii ọgbọn.

Agbara omi naa tun gbẹmi eeyan mẹtala lẹyin to sọ awọn bii ẹgbẹrun mẹfa di alainilelori.

Ipinlẹ Rivers

Ninu oṣu Karun un ọdun 2025 ni ilẹ ya lẹyin ojo kan niluu Okrika, eyii to bo awọn eeyan mọlẹ.

Eeyan marunlelọgbọn ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ nigba naa.

Agbara ojo ni Adamawa

Oríṣun àwòrán, Ahmadu Umaru Fintiri

Ọna bayọ si iṣẹlẹ omiyale ni Naijiria

Wayi o, onimo kan nipa ọrọ ayika, Ọmọwe Yusuf Idris Garba ni fasiti Bayero to wa niluu Kano ti sọ pe, ọna kan boogi ti ijọba fi le dẹkun isẹlẹ omiyale ni Naijiria ni ko gbẹ awọn gọta ti omi yoo maa gba kọja.

Lẹyin eyi, o ni awọn araalu ni lati dẹkun bi wọn ṣe n da idọti si awọn ibi to yẹ ki omi maa gba kọja.

Ọmọwe naa fikun pe ayipada oju ọjọ naa wa lara nnkan to n fa iṣẹlẹ omiyale kaakiri agbaye.

O wa rọ ijọba lati ṣe awọn ohun to yẹ lati koju ayipada oju ọjọ ọhun.