"Bàálù tó ń wa ara rẹ̀,'Drone' ni Boko Haram ń ló báyìí láti kọlu ọmọ ogun Naijiria"

Drones

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn onimọ nipa eto abo ni Naijiria ti sọ pe baalu kekere ‘Drone' lawọn agbesunmọmi n lo lati kọlu awọn ọmọ ogun Naijiria bayii.

Ọmọwe Kabiru Adamu, to jẹ onimọ nipa eto aabo sọ pe ninu oṣu kejila ọdun to kọja, igba mẹrin ọtọtọ lawọn agbesunmọmi naa gbe ado oloro si ara ẹrọ 'drone' lati kọlu awọn ọmọ ogun.

Kabiru ṣalaye pe kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn kọlọrọsi ẹda naa n lo imọ ẹrọ fun ikọlu.

Ileeṣẹ ologun ni lilo awọn ẹrọ drone ni apa ariwa le ṣakoba fun abo orilẹ ede Naijiria

Wayi o, ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria to n koju Boko Haram ni iha ariwa Naijiria ti fofin de ẹrọ 'drone' lagbegbe ọhun latari bi Boko Haram ṣe n lo o.

Ileeṣẹ ọmọ ogun naa sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn gbe ofin naa kalẹ, sibẹsibẹ awọn eeyan kan ṣi n lọ ẹrọ ọhun nibẹ lai gba aṣẹ.

Wọn ni ẹrọ naa lawọn eeyan fi n ṣe ami awọn agbofinro nibẹ.

Ọrọ yii lo jẹyọ ninu atẹjade kan ti adari ikọ Joint Task Force, Operation Hadin Kai to n koju Boko Harama ati ISWAP, Air Commodore UU. Idris fi lede.

Ileeṣẹ naa ni lilo awọn ẹrọ wọnyii ni iha ariwa le ṣakoba fun abo orilẹ ede Naijiria.

Ṣaaju ki awọn ọmọ ogun to fofin de lilọ awọn ẹrọ naa, oniruru ileesẹ, awọn oluwadii imọ ijinlẹ, atawọn akọroyin lo n lo awọn ẹrọ ọhun fun iṣẹ oojọ wọn.

Ọmọwe Kabiru sọ pe fun irufẹ awọn eeyan wọnyii, o ni awọn alakalẹ ti wọn gbọdọ tẹle ki wọn to le maa lo awọn ẹrọ naa.

Onimọ nipa eto abo ọhun pari ọrọ rẹ pe ti ofin ti wọn fi de ẹrọ 'drone' naa ba mulẹ daadaa, yoo ṣe iranlọwọ fun eto abo iha ariwa ati gbogbo Naijiria lapapọ.