Wo bí Taliban ṣe ń fi ẹ̀rọ ayàwòrán dọdẹ ayé mílíọ̀nù èèyàn ní Afghanistan

Aworan awon Taliban to n tọpinpin awon olugbe Kabul
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ninu yara nla kan ti wọn gbe ọpọlọpọ ẹrọ amohunmaworan si ara ogiri rẹ ni awọn ọlọpaa Taliban, lorilẹede Afghanistan, ti n ṣafihan ẹrọ kamẹra ẹgbẹrun lọna aadọrun-un (90,000) ti wọn ṣẹṣẹ ra, eyi ti wọn fi n tọpinpin igbesi aye awọn eeyan to le ni miliọnu mẹfa lorilẹede naa.

"Gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ni Kabul la n tọpinpin rẹ nibi."

Ọkan lara awọn agbẹnusọ ọlọpaa Taliban, Khalid Zadran, lo ṣalaye bẹẹ fun BBC nigba to n ṣafihan fọn-an-ran fidio kan.

Bo tilẹ jẹ pe awọn alaṣẹ ilu naa sọ pe awọn n tọpinpin naa lati ṣẹgun iwa ọdaran ni, sibẹ, awọn eeyan kan gbagbọ pe wọn n lo o lati maa fi pa araalu lẹnu mọ ni, ati lati ri awọn ti ko ba tẹle ilana imura Afghanistan.

Ofin wọn ni pe obinrin gbọdo lo hijaabu, o gbọdọ bo oju bi yoo ba jade sita, wọn ko si gbọdọ sọrọ nita gbangba.

Wọn tun maa n wo o boya ọkunrin da irungbọn si tabi bẹẹ kọ.

BBC ni ileeṣẹ iroyin akọkọ ti wọn gba laaye lati ri bi wọn ṣe n fi kamẹra rẹpẹtẹ naa tọpinpin.

Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é?

Khalid Zadran
Àkọlé àwòrán, Khalid Zadran

Ninu yara itọpinpin naa, awon ọlọpaa yoo jokoo yipo tẹlifiṣan ti wọn ti to papọ lati maa ri ohun to n lọ nita.

Awọn ẹrọ amohunmaworan naa ni yoo maa gbe aworan awọn eeyan miliọnu mẹfa ti wọn wa ni Kabul wa si oju iworan awon ọlọpaa yii.

Gbogbo ohun to n lọ pata ni wọn n ri, bẹrẹ lati oju wọn lọ.

"Bi a ba ri awọn eeyan kan ti wọn kora jọ lagbegbe kan ti wọn n fa igbo tabi huwa ibajẹ kan, a maa pe ọlọpaa lẹsẹkẹsẹ lati mu wọn.

"Awọn ọlọpaa maa debẹ kia wọn a si ṣewadii ohun to n ṣẹlẹ."

Zadran lo sọ bẹẹ.

Labẹ iṣakoso to kọja, Kabul jẹ igboro ilu to n koju ikọlu awon Taliban ati IS.

Iwa ọdaran ati ijinigbe si wọpọ nibẹ gan-an.

Nigba ti awon Taliban gbajọba ni 2021, wọn pinnu lati kapa awọn ọran yii.

Wọ́n kó kámẹ́rà jọ

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bi awọn Taliban ṣe lọọ ko obitibiti kamẹra jọ nitori aabo ilu bi wọn ṣe wi, ṣafihan igbiyanju wọn lati ri i pe iwa ọdaran dinku

Ki Taliban too gbajọba, kamẹra 850 lo wa ni olu ilu, gẹgẹ bi agbẹnusọ ijọba kan ṣe sọ.

Ṣugbọn latigba ti Taliban ti gbajọba, wọn ti ṣe awọn ofin kan to n tẹ ominira awon eeyan mọlẹ.

Ohun ti wọn fi han BBC ninu itọpinpin yii ni pe awọn n fi oju dọdẹ awọn eeyan.

Ni kọrọ yara kan ni wọn gbe tẹlifiṣan mi-in si to n ṣafihan oju ati ọjọ ori awọn eeyan, ati boya ọkunrin ni wọn tabi obinrin.

Bakan naa lo n ṣafihan boya wọn da irungbọn si tabi bẹẹ kọ.

"Bi igboro ba farahan daadaa, a le ya oju ẹni to wa ni ẹgbẹlẹgbẹ maili si wa bo ṣe wu ko jinaa to."

Zadran lo ṣalaye bẹẹ nigba to n nawọ si kamẹra kan ti wọn so mo adugbo kan ti ero ti pọ.

Kamẹra yii kan naa ni awọn Taliban fi n dọdẹ awọn oṣiṣẹ rẹ.

Bi wọn ba da ọkọ duro, kamẹra ti yoo ka ohun ti wọn n ṣe silẹ ti wa nibẹ.

Ileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle niluu naa sọ pe iwa ọdaran ti dinku jọjọ nigba tawọn ti gbe kamẹra de, ṣugbọn ohun to sọ naa ko ṣee fidi ẹ mulẹ, latari ai si ẹri to n tọka si i.

Bakan naa ni awọn ajafẹtọọ ọmọniyan n sọrọ lori ilana ti wọn n gba tọpinpin yii.

Wọn ni awọn wo ni wọn n tọpinpin ẹ, igba wo si ni eyi yoo dopin.

Ajo Amnesty International sọ pe eyi le jẹ ọna kan ti Taliban fi fẹẹ maa gbe ofin onikumọ rẹ le awọn eeyan lori, eyi ti yoo tẹ ẹtọ awọn eeyan mọlẹ, paapaa awọn obinrin.

Òfin de àwọn ọmọbìnrin láti má lọ síléèwé girama àti iléèwé gíga

Fariba
Àkọlé àwòrán, Fariba

Wọn ti fi ofin de awọn ọdọmọbinrin lati ma ṣe tẹsiwaju lọ sileewe girama ati ileewe giga lẹnu ẹkọ wọn.

Iwe alakọọbẹrẹ ti wọn ba ti ka ni wọn fi aaye gba wọn mọ.

Ọpọlọpọ iṣẹ ni wọn ti fi ofin de awọn obinrin pe wọn ko gbọdo ṣe.

Losu Kejila to kọja, awọn nọọsi obinrin ti wọn n ṣiṣẹ igbẹbi, sọ fun BBC pe awọn ko ni i pada sileewe mọ.

Bo si tilẹ jẹ pe wọn ko fofin de wọn lati ma rin lojuu popo,ofin Kabul ni pe obinrin gbọdọ bo oju rẹ bi yoo ba rin nigboro.

Ọmọbinrin kan to kawe jade ileewe giga, Fariba, sọ fun BBC pe oun n gbe lọdọ awọn obi oun ni Kabul.

O ni ko rọrun foun lati ri iṣẹ ṣe boun ṣe n gbiyanju to, eyi si ri bẹẹ latigba ti Taliban ti gbajọba bo ṣe sọ.

Fariba sọ fun BBC pe ẹru n ba oun pe wọn yoo lo ẹrọ kamẹra lati mu awon obinrin ti ko ba lo hijab, ti wọn si n jade lati waṣẹ ṣe.

" Ẹ̀rù n ba ọpọ eeyan lati sọrọ tako Taliban, koda awọn to jẹ ajafẹtọọ gan-an ko le sọ nnkan kan, wọn yoo yaa sa pamọ ni kaka ki wọn tako Taliban''

Fariba lo ṣalaye bẹẹ fun BBC.