Ibi tí ìpalẹ̀mọ́ dé dúró rèé ní ìlú Oyo ní ìgbáradì fún ayẹyẹ ìwúyè Aláàfin

Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti ní gbogbo ètò ló ti tò láti ṣe ìwúyè Aláàfin ìlú Oyo tuntun, Ọba Akeem Owoade lọ́jọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹrin, ọdún 2025.
Gbogbo àwọn ààyè tó ṣe kókó ní ìlú Oyo ni àwọn agbófinró ti wà níbẹ̀ láti ṣe àrídájú rẹ̀ pé ètò náà lọ ní ìrọ̀wọ́ rọsẹ̀.
Níṣe ni ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá àtàwọn agbófinró ti wà káàkiri gbogbo ìlú Oyo tó fi mọ́ Owoade, Jabata, Akesan, Isale Oyo, Eleekara àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ní ọjọ́ Kẹtàlá, oṣù Kìíní ni Gómìnà Seyi Makinde gbé ọ̀pá àṣẹ àti ìwé ẹ̀rí lé Ọba Owoade lọ́wọ́ nílé ìjọba tó wà ní ìlú Ibadan.
Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Kẹta ni Aláàfin tuntun náà parí Oro Ipebi, tó sì dé Ade Kòso lọ́jọ́ náà.

Níbo ni ayẹyẹ ìwúyè Aláàfin yóò ti wáyé?
Ilé ẹ̀kọ́ Oliveth Baptist High School ìlú Oyo ni ayẹyẹ ìwúyè náà yóò ti wáyé lọ́jọ́ Kẹrin, oṣù Kẹrin níbi tí ìrètí wà pé Gómìnà Seyi Makinde yóò kó àwọn èèkàn ìlú sòdí láti kópa níbi ayẹyẹ náà.
Àwọn gbọ̀ngàn mìíràn tí ayẹyẹ náà tún máa wáyé níbẹ̀ ni Ladigbolu Grammar School, Durbar Stadium, pápá ìṣeré Oba Lamidi Adeyemi àti ààfin ìlú Oyo.
Lára àwọn èèkàn tí ìrètí wà pé wọ́n máa kópa níbi ayẹyẹ náà ni olóòtú ìjọba tẹ́lẹ̀ rí ní Canada, Justin Trudea, àwọn aṣojú orílẹ̀ èdè mẹ́rin, àwọn orí adé, ọrùn ìlẹ̀kẹ̀, àwọn ọmọ ìlú Oyo tó wà ní Canada, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Ìròyìn ní kò sí yàrá kankan tó ṣófo mọ́ ní àwọn ilé ìtura tó wà nílùú Oyo bí wọ́n ti ṣe gba gbogbo rẹ̀ tán ní ìgbáradì fún ayẹyẹ náà.
Bákan náà ni ọjà Akesan àtàwọn ọjà tó wà ní agbègbè Oyo yóò wà ní títìpa lásìkò ayẹyẹ ìwúyè Aláàfin tuntun.
















