Ṣé lóòótọ́ ni àwọn agbénipa ṣèkọlù sí Ondo, tí wọ́n gé orí àti apá?

Aworan

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ikọlu to bani ninu jẹ ti waye ni ijọba ibilẹ Akoko ni ipinlẹ Ondo ni Ọjọ Satide.

Eyi ko ṣẹyin awọn agbegbọn ti wọn ṣekọlu si agbegbe meji ti wọn si pa awọn ẹṣọ alaabo meji nibẹ.

Ikọlu naa waye ni agbegbe meji ọtọọtọ ni ijọba ibilẹ naa.

Sé lóòtọ́ ni àwọn agbénípa gé orí àti apá awọn ti wọn pa?

Iroyin ni awọn agbebọn naa ni wọn tun ge ori ati ọwọ awọn ti wọn pa naa.

Ọkan lara awọn oṣojumikoro to ba awọn oniroyin sọrọ ni ọja Mimiko ni ikọlu naa ti waye, ti ekeji si waye ni ileẹkọ NASFAT ni ilu naa.

‘’Ọkan lara awọn ti wọn pa naa ni wọn ba oku rẹ ni owurọ Ọjọ Satide ninu ẹjẹ, ti wọn ti ge ori rẹ ti wọn si fi si ẹgbẹ rẹ’’

‘’Bakan naa ni wọn ge ọwọ ẹnikeji ti wọn pa ti wọn si tun fi si ẹgbẹ ara rẹ to ku.’’

‘’Awọn agbenipa naa ko mu ohunkohun kuro nibi ti wọn ti pa awọn eniyan naa.’’

Awọn ti wọn ri oku naa ni bi wọn ṣe pa awọn eniyan naa ṣeeṣe ko jẹ etutu ni wọn fi wọn ṣe.

Bakan naa ni iroyin fikun un pe ileeṣẹ ọlọpaa ni Ikare lo wa gbe oku awọn mejeeji ọhun lọ si ile igbokusi ni ileewosan Ondo State Specialist Hospital, Ikare Akoko.

Ko si ohun to jọ pe wọn ge ara oku ni ikọlu Akoko - Ileeṣẹ ọlọpaa Ondo

Amọ ileeṣẹ ọlọpaa to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni ko si ara kankan ti wọn gẹ lọ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo. Funmilayo Odunlami ni wọn ko ge ara kankan

wọn fikun un pe lootọ ni wọn pa awọn ẹṣọ alaabo meji ni ibi mejeeji ọtọọtọ.

O ni ibi akọkọ ni ọlọde to n sọ ọja Mimiko, ti ọlọde keji ti wọn pa ṣi n ṣọ ileẹkọ NASFAT ọhun.

Bakan naa lo ni ẹni aadọrin ọdun ati ẹni ọdun marundinlọgọrin ni awọn ọkunrin ti wọn pa ọhun.