2021 World Teachers Day: ọdún tó n bọ̀ lowó oṣù tuntun fáwọn olùkọ́ Nàìjíríà yóò di gbígbà...

Students for class

Oni ni ayajọ awọn olukọni lagbaye.

Ajọ UNICEF ati ILO to fi mọ Educational Internation lo maa n ṣagbatẹru eto ayajọ yi.

Lorileede Naijiria bi tawọn ilẹ miran ti iṣẹ olukọ ti gbajumọ, pupọ lo n fi ọjọ yi ṣagbeyẹwo iṣẹ olukọ,ipenija ati afojusun ọjọ iwaju.

Akori ayajọ ti ọdun yi ni ''Teachers at the Heart of Education Recovery'' eyi to tumọ si ipa tawọn olukọ n ko ninu ijipada eto ẹkọ.

Akori yi ṣe pataki paapa ti a ba wo bi ajakalẹ Covid-19 ti ṣe mu iyipada ba eto ẹkọ ti ọpọ akẹkọọ ko si ribi kẹkọ ni kilaasi bi tatẹyinwa.

Lawọn orileede ti ọwọja aarun yi ti peleke, titi di asiko yi, awọn akẹkọọ ko ribi pada si kilasi ti eyi si mu ifaṣẹyin ba ẹkọ wọn.

Àkọlé fídíò, Teachers retirement age and years of service: Ìrírí àwọn àgbà olùkọ́ ṣì wúlò fún àwa ọ̀dọ́

Ni Naijiria awọn olukọ ati akẹkọọ ti pada si kilasi ti eto gbogbo ṣi n lọ ṣugbọn awọn ipenija to ba eto ẹkọ mii ṣi wa.

Diẹ ninu wọn ni ipenija aabo paapa ọrọ ijinigbe awọn olukọ ati akẹkọọ lawọn ile ẹkọ lati alakọbẹrẹ to fi de fasiti.

Aranmo

Amọ ọkan ninu ipenija ti ọpọ n mẹnu ba ni eleyi to ni ṣe pẹlu owo oṣu awọn olukọ ti ko to lati fi gbọ bukata.

Laipẹ yi ni ijọba Naijiria kede pe awọn yoo ṣe afikun owo oṣu olukọ lọna ati mu ki awọn ọlọpọlọ pipe wa si idi iṣẹ olukọni.

Àkọlé fídíò, Alakuko/Elega Schools: Aráàlú ní olùkọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ti sá ní kíláàsì tí kò dára

Yatọ si afikun owo oṣu yi, aarẹ Buhari kede awọn moriya bi eto ile igbe,owo ajẹmọnu ati igbaradi loore koore fawọn olukọ.

Minisita feto ẹkọ Naijiria Chukwuemeka Nwajuba sọ laipẹ yi pe ọdun to n bọ 2022 lawọn olukọ yoo bẹrẹ si ni gbadun afikun owo oṣu yi.

Àkọlé fídíò, Adepoju Abdulsalamm ẹni ọdun 18 tó n fi kẹ̀kẹ́ dára fi kiri ẹja tó fi n tà wàràwàrà

O fi ọrọ naa lede nibi apero idanilẹkọ kan to waye ni Abuja lara eto ayajọ olukọ ni Naijiria.

Minisista ọhun sọ pe awọn ṣe gbogbo eto lati ri pe awọn olukọ gba owo oṣu to tọ si wọn loṣu kini ọdun 2022.

Àkọlé fídíò, Ọ̀ṣọ́ Aṣọ Òkè ti kọjá lílo ìlẹ̀kẹ̀ níkan

''Aarẹ ti buwọlu afikun owo yi, a si n gbiyanju lati ri pe o gberasọ ni ọdun 2022''

O fi kun pe ''Aarẹ ti lewaju nipa ṣiṣe agbekalẹ ilana ti yoo mu iyipada ba iṣẹ olukọni ni Naijiria.''

Àkọlé fídíò, Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Adarí FIN

Ati pe ''ohun to ku ni ki awọn alẹnulọrọ bi awọn Gomina,ile aṣofin ati awọn mii darapọ mọ eto yi ko ba le kẹsẹjari''